Àjọ EFCC mú ẹ̀rí tuntun lọ sílẹ̀ ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ Emefiele

Aworan Godwin Emefiele

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorileede Naijiria tun ti kọ awọn ẹri miran silẹ fun ile-ẹjọ lori awọn ẹsun iwa jibiti ti wọn fi kan gomina banki apapọ Naijiria tẹlẹ ri, Godwin Emefiele.

Rotimi Oyedepo to jẹ agbẹjọro EFCC lo ko awọn ẹri naa kalẹ siwaju ile-ẹjọ, lati le jẹ ki ile-ẹjọ naa mọ pe awọn ko purọ mọ Emefiele.

Oyedepo ni awọn ẹri naa ni awọn gba lati ọdọ amugbalẹgbẹ Emefiele tẹlẹ, ṣaaju asiko ti yoo yọju siwaju ile-ẹjọ lati sọ tẹnu rẹ.

Ọjọbọ, ọsẹ yii la gbọ pe Oyedepo ko awọn ẹri naa lọ siwaju ile-ẹjọ lati ṣagbeyẹwo rẹ ṣaaju ọjọ Ẹti, ana.

Nigba toun naa n sọrọ, agbẹjọro Emefiele, Ọlalekan Ojo rọ ile-ẹjọ lati sun igbẹjọ naa siwaju di igba miran, nitori pe oun ko mọ nnkankan nipa ẹsun tuntun naa, ati pe oun nilo lati ṣagbeyẹwo rẹ daadaa.

Siwaju sii ni Ojo fi ẹsun kan Oyedepo wi pe ẹjọ to n ṣe, ko ṣe e ni ti iwa ọmọluabi, o ni niṣe lo n wa ẹsun mọ ẹsun fun onibara oun, eyi to pe ni “trial by ambush”.

Nigba to n gbe aṣẹ rẹ kalẹ, Onidajọ Rahman Oshodi sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kẹsan, oṣu karun-un, ọdun 2024.

Emefiele ati ẹnikeji rẹ, Henry Omoile ni wọn n foju ba ile-ẹjọ lori ẹsun onikoko mẹrindinlọgbọn ti ajọ EFCC fi kan wọn.