Ṣé lóòtọ́ ni Sunday Igboho ti gba ìtúsílẹ̀ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n Benin Republic?

Sunday Igoho

Oríṣun àwòrán, Igboho

Agbẹjọro oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti sọrọ lori iroyin to n lọ ni igboro pe ajijagbara naa ti gba itusillẹ.

Ọkan lara awọn agbẹjọro rẹ, Yomi Alliyu, SAN, ti sọ pe Igboho ṣi wa ni ahamọ orilẹ-ede Benin Republic tako ọrọ to n lọ ni igboro.

Ninu atẹjade kan lori ayelujara lo ti sọ ọrọ naa.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ko si ootọ kankan ni iroyin ti awọn kan ti n gbe kiri pe Igboho ti gba itusilẹ.

O ni “Lori ọrọ to n lọ laarin ilu pe wọn ti fi Igboho silẹ.”

Sunday Igoho

Oríṣun àwòrán, Yomi Alliyu

“Ẹ jọwọ ẹ maṣẹ gba iroyin naa gbọ tabi pe o ti n tẹkọ leti lọ si orilẹ-ede Germany, ko si ohun to jọ bẹẹ.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Lootọ ni iṣẹ ti n lọ lọwọ pẹlu ifọwọsowọpọ Ọjọgbọn Akintoye atawọn agbẹjọro mii bii Falola lori bii nnkan yoo ṣe rọ lọrun fun un, yatọ si inu ọgba ẹwọn to wa.”

Agbẹjọro naa pari ọrọ rẹ pe ki awọn ololufẹ Igboho lọ fi ọkan wọn balẹ ki wọn si maa fi adura ṣọwọ si Igboho nibi to wa.

Bi ọrọ naa ṣe bẹrẹ:

Ti ẹ ko ba gbabe, nnkan bii aago kan oru ni DSS kọlu ile Igboho to wa lagbegbe Soka, niluu Ibadan, iyẹn lọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun to kọja.

Ikọlu naa lagbara to bẹẹ ti ẹmi eeyan meji sọnu, nigba ti wọn fi ṣikun ofin mu awọn mejila miran, amọ Igboho moribọ.

Ẹwẹ, lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2021 kan naa ni Igboho ti wa lọgba lorilẹ-ede Cotonou, ti ijọba orilẹ-ede naa ko si fi ẹsun kankan kan an.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ