Adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Ogun dá ẹlẹ́wọ̀n mẹ́ta sílẹ̀, ó ní kí wọ́n má d’ẹ́ṣẹ̀ mọ́

Aworan moto elewon

Oríṣun àwòrán, Channels TV/Web

Adajọ agba nipinlẹ Ogun, Onidajọ Mosunmọla Dipẹolu ti buwọ lu itusilẹ ẹlẹwọn mẹta ọtọọtọ, to si ni ki wọn maa lọ lai da ẹṣẹ mọ.

Joseph Apan, Nureni Oladoṣu, ati Babatunde Fagbayi lawọn ẹlẹwọn mẹta naa ti Onidajọ Dipẹolu ni wọn maa lọ sile layọ ati alaafia.

Onidajọ Dipẹolu lo kede yii lasiko abẹwo to ṣe lọ si ọgba ẹwọn to wa niluu Ilaro, ijọba ibilẹ Yewa South lojuna lati din awọn ero ọgba ẹwọn ku nipinlẹ naa.

Nibẹ lo ti sọ pe awọn onidajọ, alakoso eti idajọ, awọn alẹnulọrọ, to fi mọ awọn alakoso ati oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ni wọn daba naa.

O ni awọn ko le laju silẹ lati maa padanu awọn ẹlẹwọn, idi ree to fi ni awọn nilo lati din awọn ẹlẹwọn ku, ki wọn ma ba a pọ lapọju.

Ninu ọrọ rẹ, oni “Ipo ti ọgba ẹwọn ko tii yipada, eyi si jẹ idaniloju wi pe ero yoo tubọ maa pọ si nibẹ lai jẹ pe akọsilẹ gidi wa. Bi ero ṣe n pọ yii lo n kọ wa lominu, paapaa julọ awọn ti wọn ko tii da ẹjọ wọn, nitori pe wọn n jiya ẹṣẹ lai tii jẹbi okodoro foju han.”

Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ pe igbesẹ ti n lọ lati rii pe idajọ n tete waye lori awọn ti ẹjọ wọn ṣi wa niwaju ile-ẹjọ, nigba to n ṣe apẹẹrẹ awọn ti wọn ti n jẹjọ lati ọdun 2018.