Lórí ìdẹ́yẹsí ọmọ Gbenga Daniel tòní ìpèníja ara,FAAN sọ àgádágodo sí ìlé oúnjẹ KFC

Aworan onibara KFC ti wọn ṣe idẹyẹsi  Debola Daniel

Oríṣun àwòrán, @DebolaDaniel

Ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ ofurufu lorilẹ-ede Naijiria, Federal Airports Authority of Nigeria (FAAN), ti paṣẹ pe ki wọn ti ẹka ile ounjẹ igbalode KFC to wa ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed niluu Eko pa.

Ko si ṣẹyin ẹsun idẹyẹsi ti arinrinajo kan fi kan ile ounjẹ naa to kọ lati ta ounjẹ fun tori ipenija ara to ni.

Ninu atẹjade kan ti FAAN fi sita lỌjọbọ ni wọn ti sọ pe ki titi ile ounjẹ yi waye ni kiakia bẹ́ẹ lati ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu Kẹta.

Ipinnu yi gẹgẹ bi FAAN ṣe sọ wa ni ibamu pẹlu ofin ipinlẹ Eko to lodi si idẹyẹsi si ẹnikẹni to da lori ipenija ara ti onitọhun ba ni.

Igbesẹ ti FAAN gbe yi waye lẹyin awuyewuye to tẹyin ọrọ ti onibara ile ounjẹ yi kọ soju opo Twitter pe wọn hu iwa idẹyẹsi si oun nigba toun fẹ ra ounjẹ ni ile ounjẹ naa to wa ni papakọ ofurufu ipinlẹ Eko.

Bawo lọrọ ṣe de ibi to de yi

Arinrinajo ti ọrọ yi kan @DebolaDaniel lo fi iriri rẹ soju opo Twitter lọjọ Kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹta to si fi ẹhonu rẹ han lori iwa ti ile ounjẹ yi hu si.

Debola to jẹ ẹni to n lo kẹkẹ lati fi rin sọ pe lasiko tawọn fẹ jẹun ṣaaju irinajo lọ si London ni awọn oṣiṣẹ ibẹ hu iwa buruku si ohun nipa pipariwo pe ko si igbalaaye fun ẹni to ba n fi kẹkẹ rin.

Ko kọkọ darukọ ile ounjẹ naa ṣugbọn nigba ti awọn eeyan bẹrẹ si ni beere bo ti ṣe jẹ ni o fi orukọ ile itaja ounjẹ KFC soju opo rẹ to si tu kẹkẹ ọrọ naa sita faraye.

O ni aṣiṣe nla lo jẹ pe oun ya si ile ounjẹ naa tori pe arabinrin to n dari ile ounjẹ naa pariwo sita pe ko saaye fun ẹni to n fi kẹke rin nibi bayii

Skip Twitter post, 1

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post, 1

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Ọrọ naa pada di ranto ti awọn oṣiṣẹ ileeṣe yi ko si faaye gba arakunrin Debola lati joko jẹun nibẹ.

O ni niṣe ni oludari ẹka ile ounjẹ naa sọ pe ileeṣe awọn ti pawọn laṣẹ lati ma faaye gba ẹnikẹni to ba n fi kẹkẹ rin wọ inu ile itaja ounjẹ wọn.

Skip Twitter post, 2

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post, 2

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Ki ni KFC fọ lesi si ọrọ yii?

Ọrọ ti Debola kọ yi deti igbọ ileeṣẹ ounjẹ igbalode KFC ti wọn si fesi pada loju opo wọn pe awọn n ṣe iwadii ọrọ naa ati pe awọn ko faaye gba idẹyẹsi si ẹnikẹni.

Lara nkan ti wọn lawọn yoo si ṣe ni pe awọn yoo bẹrẹ idanilẹkọ fawọn oṣiṣẹ wọn lori bibọwọ fun awọn eeyan.

Wọn ko tọrọ aforijin fun iwa ti oṣiṣẹ wọn hu si alabara yi ko to di pe ajọ FAAN sọ agadagodo si ile itaja wọn.

FAAN si ti ni ki wọn kọ iwe si arakunrin naa lati tọrọ aforijin iwa ti wọn hi si ki wọn si tun kọ gbagada si ẹnu ọna ile ounjẹ wọn pe awọn ko faaye gba ilana idẹyẹsi si ẹnikẹni ṣaaju ki wọn to bẹrẹ iṣẹ pada.

Skip Twitter post, 3

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post, 3

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.