Ọlọ́pàá mú tọkọtaya tó n lu ọmọ wọn ní ìlù ẹranko ní Eko

Tọkọtaya Busola ati Emmanuel

Oríṣun àwòrán, naptip

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti mu obinrin kan ati ololufẹ rẹ, fun ẹsun pe wọn fi iya jẹ ọmọde meji, ni agbegbe Egbeda nipinlẹ naa.

Obinrin naa, Busola Oyediran, to jẹ iya awọn ọmọ naa, ati ọkọ rẹ tuntun, Akebiara Emmanuel, ni ọwọ tẹ̀ lọjọ Ẹti.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, sọ fun awọn akọroyin pe ọjọ ori awọn ọmọ naa jẹ ọdun marun-un ati ọdun meji.

Iroyin sọ pe awọn alajọgbele tọkọtaya naa, to ri bi wọn ṣe ma n lu awọn ọmọ ọhun, eyi to ti da oriṣiriṣi ọgbẹ́ si wọn lara, lo fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa l’eti.

Eyi si lo mu ki ọlọpaa fi ofin gbe wọn lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala, oṣu Kinni, 2023.

Ajọ to n gbogun ti fifi eeyan ṣe owo ẹru ati iloluko ẹ̀dá, NAPTIP, sọ loju opo Twitter rẹ pe tọkọtaya naa ti wa ni atimọle.

Bakan naa ni ajọ naa sọ pe wọn o gbe awọn mejeeji lọ sile ẹjọ, lọjọ Aje, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, 2023.