Ìjà parí! Ogogo àti Yinka Quadri dìmọ́ ara wọn lẹ́yìn tí Ajobiewe báwọn dá si

Yinka Quadri àti Ogogo

Oríṣun àwòrán, Others

Níṣe ni ẹnu ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nígbà tí ìròyìn gbòde pé àwọn àgbà òṣèré nnì Yinka Quadri àti Taiwo Hassan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ogogo ti parí ìjà.

Ìbéèrè tó gba ẹnu ọ̀pọ̀ ènìyàn ni pé ṣe àwọn méjéèjì ń jà ni?

Ṣáájú ni àwọn ìròyìn kan ti ń lọ lórí ayélujára pé nǹkan kò lọ déédé láàárín àwọn àgbà òṣèré méjéèjì láti ọdún tó kọjá àmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò gbàgbọ́.

Àmọ́ àwọn ènìyàn tún bẹ̀rẹ̀ sí ní kùn lórí ìjà wọn ọ̀hún nígbà tí Yinka Quadri kò yọjú síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó ọmọ Ogogo tó wáyé nínú oṣù Kejìlá ọdun 2023.

Yinka Quadri àti Ogogo ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn mọ̀ sí ọ̀rẹ́ wọlé-wọ̀de nítorí ipa tí wọ́n jọ máa ń kó nínú eré sinimá.

Kí ló fa ìjà láàárín Ogogo àti Yinka Quadri?

Yàtọ̀ sí pé wọ́n jọ máa ń ṣeré papọ̀, Yinka Quadri àti Ogogo ni wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ eré tíátà kan náà.

Bákan náà ni wọ́n jọ́ máa ń jáde, lọ sí òde papọ̀, nígbà mìíràn tí wọn á sì wọ aṣọ irú kan náà. Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò ó pé ẹbí ni wọ́n.

Èyí ló mú kí àwọn èèyàn máa bèrè pé kí ló le mu Yinka Quadri má yọjú síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó ọmọ Ogogo tí kò sì tún lọ síbi ayẹyẹ ìkómọjáde nígbà tí ọmọ náà tún ṣabiyamọ.

Ṣùgbọ́n títí di àsìkò yìí, àwọn àgbà òṣèré méjéèjì kò sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣokùnfà bí àwọn méjéèjì kò ṣe ṣe wọlé wọ̀de mọ́.

Níṣe ni àwọn ènìyàn ń fò fáyọ̀ nígbà tí ìròyìn gbòde pé àwọn àgbà òṣèré náà ti parí ìjà níbi ayẹyẹ kan tó wáyé ní lọ́jọ́rú.

Níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àti ìṣílé òṣèré mìíràn, Yomi Fabiyi tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Ogun ni gbajúmọ̀ akewì, Sulaiman Aremu Ajilara tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Ajobiewe parí ìjà àwọn àgbà òṣèré náà.

Nínú fídíò kan tó gba orí ayélujára ni a ti rí tí Ajobiewe ti ń rọ àwọn àgbà òṣèré náà láti parí gbogbo aáwọ̀ tó wà láàárín wọn àti pé òun kò gbọdọ̀ gbọ́ pé ohunkóhun nípa wọn mọ́.

Fídíò náà ṣàfihàn bí Yinka Quadri ṣe bọ́ síwájú Ajobiewe láti ná an lówó àmọ́ tí Ajobiewe sì bèèrè lọ́wọ́ Yinka Quadri pé kí ló dé tí kò mú Ogogo dání.

Ó ní kí Yinka Quadri pé Ogogo wá síwájú, tí Ogogo náà sì jáde síwájú níwájú Ajobiewe.

Ajobiewe wá forin sọ fún àwọn àgbà òṣèré náà pé kò sí bí èèyàn méjì yóò ṣe máa gbé pọ̀ tí kò ní sí àwọn ìfaǹfà kọ̀ọ̀kan láàáí wọn.

Ó bẹ àwọn àgbà òṣèré náà láti parí gbogbo èdè àìyedè tó bá ṣẹlẹ̀ láàárín wọn, kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ wọn mọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa ba ọ̀rẹ́ wọn lọ bíi ti àtẹ̀yìnwá.

Lẹ́yìn náà ló ní kí àwọn méjéèjì dìmọ́ ara wọn láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìjà i parí láàárín wọn àti pé òun kò fẹ́ gbọ́ nǹkankan mọ́ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ yìí.

Àwọn àgbà òṣèré náà sì sọ̀rọ̀, rẹ́rìn-ín síra wọn kí wọ́n tó dìmọ́ ara wọn.

Fídíò náà ti ń fa kí àwọn èèyàn máa sọ̀rọ̀ lórí ayélujára.

Skip Twitter post

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.