Ọlọ́pàá mu pásítọ̀ àti àwọn méjì mìírán fún ìpànìyàn ní Ogun

Awọn afurasi

Oríṣun àwòrán, Ogun state police

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ pasitọ kan ati eeyan meji mii fun ẹsun pe wọn ji arakunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Adekunle Muyiwa gbe, wọn si tun pa a.

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa, Idowu Abel, Clement Adeniyi, ati Pasitọ Felix Ajadi.

Ọwọ tẹ wọn lẹyin ti ọkunrin kan, Oluwaseyi Adekunle, to jẹ ẹgbọn ọkunrin ti wọn pa, fi ẹjọ sun pe aburo oun kuro nile lati ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun 2022, ti ko si pada sile.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi sọ pe ni kia si ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Owode-Yewa bẹrẹ iwadii lori bi ọkunrin naa ṣe di awati.

Iwadii wọn lo fihan pe Idowu Abel lo wa a gbe ẹni ti wọn n wa lati ile rẹ lọjọ to di awati.

Abel jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe ọrẹ timọtimọ oun ni Oloogbe Adekunle Muyiwa, ati pe oun fi ẹ̀tàn pe e jade nile rẹ.

“Lẹyin naa ni wọn jọ lọ si oko Clement Adeniyi, nibi ti wọn ti pa a , ti wọn si tun ge ẹran ara si wẹwẹ.

Ọgbẹni Idowu Abel tun sọ fun awọn ọlọpaa pe babalawo kan ti Pasitọ Felix Ajadi mu oun lọ si ọdọ rẹ, lo beere fun ori eeyan, ọkan, ọwọ meji ati ẹsẹ meji.

Bakan naa lo ni babalawo ọhun to ti salọ bayii, ṣe ileri lati san ẹgbẹrun lọna igba Naira fun oun, to ba fi ba a ri awọn ẹya ara eeyan naa.

O ti san ẹgbẹrun lọna ọgọrin Naira silẹ, to si jẹjẹ lati san eyi to ku ti Abel ba ko awọn ẹya ara wa.

Iroyin sọ pe ọrẹ ọjọ pipẹ ni Idowu Abel ati Adekunle Muyiwa.

Ohun lo si jẹ ki o rọrun fun Abel lati sọ fun ọrẹ rẹ pe ko sin oun de ibi kan.

Ṣugbọn niṣe ni oun ati Clement Adeniyi pa a sinu oko, wọn yọ ọkan, wọn ge ori rẹ, wọn si sin iyoku ara rẹ sinu iho kan ti kan ti wọn gbẹ́.

Ọgbẹni abel ni ọwọ ọlọpaa kọkọ tẹ, to si mu wọn lọ si ọdọ Pasitọ Felix ati Clement Adeniyi.

Babalawo ọhun ti sa lọ.

Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti paṣẹ ki wọn gbe awọn afurasi naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n wadii ẹsun ọdaran.