A kú àmójúbà!!! Ààrẹ Buhari yóò ṣé  ìfilọ́lẹ̀ owó tuntun lónìí

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Gomina banki apapọ lorilẹede Naijiria, Godwin Emefiele ti kede pe Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣe ifilọlẹ awọn owo tuntun, N1,000, N500 ati N200 lonii.

Emefiele ṣe ikede yii nibi ipade awọn igbimọ baanki lorilẹede Naijria to maa n waye loṣooṣu niluu Abuja.

Gẹgẹ bii o ṣe sọ, o ni banki apapọ yoo ṣe afikun si ọjọ ti wọn fun eeyan lati ko awọn owo tẹlẹ waa si banki lati gba tuntun.

Emefiele lo kede lọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹwaa pe awọn yoo gbe awọn owo tuntun jade, ti yoo si wa si imusẹ lọjọ kẹẹdogun oṣu kejila ọdun yii ṣugbọn asiko maa wa ti awọn owo tẹlẹ ọhun ko le ṣe igba mọ, eyi ti wọn ni titi ọjọ kọkandinlọgbọn ni awọn fun wọn da.

Sugbọn o kede lana ọjọ Isẹgun pe banki apapọ ko ni le duro di ọjọ kẹẹdogun oṣu kejila mọ nitori pe Aarẹ ti ṣetan lati ṣe ifilọlẹ awọn owo naa lonii.

“Ọgọrun ọjọ ti to fun ẹnikẹni lati origun mẹrin orilẹede yii lati lọ kowo rẹ ti tẹlẹ lọ si banki, ko si gba owo rẹ pada ti a ba gbe owo tuntun jade.

“Lagbara Ọlọrun, lọla, to jẹ ọjọ kẹtalelogun oṣu kọkanla ọdun 2022, Aarẹ yoo ṣe ifilọlẹ awọn owo tuntun niluu Abuja ni dede ago mẹwaa.”