‘Pẹ̀lú ike 10,000 táa fi bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé yìí, àwọn èèyàn ríi, ẹnu ń yà wọ́n’

Olukọ ni Dokita Bello Adebayo ni ile ẹ́kọ gbogboniṣe to wa ni ilu Ilorin nipinlẹ Kwara.

“A ko bii ike rọba gbẹrun mẹwa jọ a si ko wọn sinu oorun”.

O ni awọn ṣe eyi lati mọ boya awọn kan yoo fọ, lootọ awọn fọ, ideri awọ́n mii jẹra.

Ile onike

Wọn fẹ fi eyi mọ bi awọn ike naa ṣe le lọjọ lori to.

“Iyẹpẹ yanrin ti awọn Sọja maa n ko lati fi kọle fi ṣe ayẹta ni a lọ ko
Bi wọn ṣe n gbẹ ipilẹ na la ṣe gbẹ ipilẹ rẹ ti a si tun ṣe kọnkere toripe ẹru ti yoo ru pọ̀”.

Ile onike

Ki lo sun olukọ yii debi a n fi ike kọle?

Ile onike

“Emi jẹ ẹnikan to fẹran ayika to si maa n awọn ẹbun Ọlọrun torinaa emi naa ri bii ohun ti a gbọdọ tọju”.

O maa n ba mi ninu jẹ bi awọn eeyan ṣe maa n lo ayika, agbegbe wa ti wọn a maa ṣe nnkan ibajẹ sibẹ”.

O woye pe ike lo gba ipo ikini ninu gbogbo nnkan to maa n fa idọti ju ladugbo.

“Mo rii pe eleyi ko pọ to owo taa fi kọ ti oni bulọọku ti yoo si maa ṣe iru anfani kan naa ti a fẹ ko ṣe. Koda eleyi tun wa rẹwa”.

“Kò sẹ́ni tó kọjá ládùúgbò yìí, wọ́n ó máa wòó ni pé kí leléyì tó rẹwà tó yááyì lójú yìí”

Ki ni ile yii yoo wulo fun?

Ile onike

Dokita Bello ni awọn kọ ile naa fun awọ́n ẹṣọ aláàbò ilé ẹkọ.

“Bí àwọ́n ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn bá ń jà, “Bullet proof” ni ilé yìí jẹ́”.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí