Mo ta ọkọ̀ ayọkẹ́lẹ́ méjì lórí àìsàn yìí, mo nílò ìrànwọ́ ẹ̀yin olólùfẹ́ mi – Iyabo Oko

Iyabo Oko

Oríṣun àwòrán, iyabo_oko

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba to dubulẹ aisan, Iyabo Oko, ti ke si awọn ololufẹ rẹ lati ṣe iranlọwọ owo fun ko le fi tọju aisan to n ba finra.

Iyabo Oko lo fi ẹbẹ naa lede lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori aisan to n ba finra.

Agba oṣere naa kọkọ dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ fun aduroti wọn lati igba ti wọn ti gbọ pe o n ṣaisan, o si ṣe adura fun wọn pe wọn ko ni fi iru rẹ gba a.

O sọ pe oun ti n gbadun, bẹẹ si ni alaafia ti n de ba agọ ara oun ju ti iṣaaju lọ, amọ o ku ni bọn n ro.

Iyabo Oko ni “Ara mi ti n ya, mo ti n wa ok, ṣugbọn mo ṣi nilo adura ati owo.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọkọ ayọkẹlẹ meji ni oun fi n ṣe ẹsẹ rin tẹlẹ, ṣugbọn oun ti ta awọn ọkọ naa lati le ri owo fun itọju.

Agba oṣere naa sọ pe “Iṣẹ ti mo fẹ ran si awọn ololufẹ mi ni pe, mọto n jẹ mi niya gan.”

“Mọto meji ni mo ni tẹlẹ, ṣugbọn mo ti ta ọkọ mejeji lẹyin ti aisan yii bẹrẹ, iya mọto si n jẹ mi bayii”

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iyabo Oko ni ọpọ igba ti oun ba fẹ lọ sile iwosan ni kii si ọkọ ti yoo gbe oun lọ sibẹ.

O ni “Igba miran ti mo ba fẹ lọ sile iwosan a kii ri mọto, awọn to ni mọto ni adugbo yoo maa sọ pe ko si ọkọ wọn nilẹ.

“Nigba mii ẹwẹ, awọn miran a sọ pe wọn ti fi ọkọ wọn ran eeyan niṣẹ, nitori naa ni wọn ko ṣe le gbe silẹ fun mi. Iya ọkọ n jẹ mi pupọ.”

Iyabo Oko pari ọrọ rẹ pẹlu idupẹ ati adura fun awọn ololufẹ rẹ, to ti n na ọwọ si lati igba ti aisan ọhun ti bẹrẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọdun 2015 ni Iyabo Oko kọkọ dubulẹ aisan, ti ẹni to duro gẹgẹ bii akọbi ọmọ rẹ ọkunrin si gbe lọ silẹ India fun itọju, nibi to ti lo ọdun kan.

Lẹyin to pada de Naijiria, lo tun tẹkọ leti silẹ Gẹẹsi, o gbadun, amọ nnkan bii ọsẹ melo kan sẹyin ni aisan naa tun bẹrẹ.