FFK ti kó èébì rẹ̀ jẹ, Buhari dáa pẹ̀lú bó ṣe gba ọmọ onínàákúnàá padà – Femi Adesina

Femi Adesina ati Fani Kayode

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

FFK ti ko eebi rẹ jẹ, Buhari dara pẹlu bo se gba ọmọ oninakuna pada sile – Femi Adesina

Bi minisita feto irinna ofurufu tẹlẹ, Femi Fani-Kayode, FFK se pada sinu ẹgbẹ oselu APC to ti kuro lọ si PDP, lo se afihan pe aja rẹ ti ko eebi ara rẹ jẹ.

Oludamọran pataki si aarẹ Buhari feto iroyin, Femi Adesina lo woye ọrọ yii ninu ọrọ apilẹkọ nipa isẹ aarẹ to maa n gbe jade lọsọọsẹ.

Adesina ni igbesẹ kiko eebi jẹ ti FFK gbe nira pupọ, aimọye ọpọ eeyan si ni ko le se iru rẹ.

Adesina ni “Tẹ ba woo daa daa, se o rọrun rara ki eeyan ko eebi ara rẹ jẹ? Rara o. Amọ ohun ti FFK se ree.

Ẹ wo gbogbo awọn ọrọ kobakungbe ti Fani-Kayode ti sọ si aarẹ Buhari ati ijọba rẹ, ẹgbẹ oselu APC atawọn eeyan mii to wa ninu ijọba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Gbogbo awọn ọrọ yii ni FFK ko jẹ, se o wa dun lẹnu rẹ ni? Rara o, puẹ, eebi gan yoo maa gbe eeyan.

Nitori naa, ẹ jẹ ka kan saara si iwa akikanju to hu, iru abuda yii ko sọwọn, kii si se ọpọ eeyan lo le se iru rẹ.”

Nigba to n salaye idi ti Buhari fi gba FFK pada si agbo ẹgbẹ APC, o ni oju aanu nla ni aarẹ si wo Fani-Kayode yii lati gba ọmọ oninakuna rẹ pada sile.

“Bi aarẹ Buhari se gba FFK pada, to si gbalejo rẹ nile ijọba Aso Rock, se afihan ẹmi idarijin nla, isiju aanu wo ni ati asa ẹ jẹ ki ohun to ti kọja, maa kọja lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eeyan melo lo le se iru eyi, wọn ko pọ rara.

Buhari siju aanu wo FFK, bii iri aanu to n ṣẹ lati ọrun amọ to ba jẹ ẹyin ni, ẹ tutọ soke, fi oju gbaa ni, tẹ si ni bi FFK ba le ku, ko lọ ku.

Amọ Buhari ko se eleyi amọ o se afihan abuda Ọlọrun ọba, tii se nini ẹmi idarijin.

Amin iyasọtọ kan

Ìjọba ẹ má wòran, àjà ilé Aṣòfin tó ń jò le wó lé wa lórí – Aṣòfin sọ̀rọ̀ ṣókè!

Ile Igbimo Asofin to n jo

Oríṣun àwòrán, Others

Adari awọn ọmọ ile Aṣofin to kerejulo, Ndudi Elumelu ti kegbare pe ẹmi awọn wa ninu hila hilo pẹlu ile aṣofin to n jo le wọn lori ni gbogbo igba.

Elumelu to wa lati ẹgbẹ oṣelu PDP ni omi to n jo ni gbogbo igba le wọn lori fihan pe aja Ile Aṣofin ti baje, ti o si le wo nigba kugba.

O ni o lewu ki awọn aṣofin ma a ṣepade ijoko ile ni iru agbegbe bẹẹ lai naani ẹmi wọn to wa ninu ewu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adari awọn ọmọ ile Aṣofin to kere julọ naa wa kesi awọn alaṣẹ Ile Igbimọ Aṣofin lati tete wa nkan ṣe si ọrọ naa ni wara n ṣesa.

”Ohun to n ṣẹlẹ ni Ile Igbimọ Aṣofin yin n kọ mi lominu lo jẹ ki n dide sọrọ ni asiko yii.”

”Olori ile, ti ẹ ba wo yika, ẹ o ri pe omi lo yi wa ka nitori aja ile Asọfin n jo, ti a si gbọdọ wa nkan ṣe si ni kiakia, nitori ko si ẹnikẹni to le e sọ nkan to le e ṣẹlẹ.”

Ile Igbimo Asofin to n jo

Oríṣun àwòrán, Others

”Ko si igba ti a wa si ibi yii ti awọn gbalẹ-gbalẹ ko si nibẹ, ti wọn n ko omi to n jo si inu ile aṣofin, eleyii si lewu pupọ ni oju mi.”

”Ko ṣeeṣe ki a ma a ṣiṣẹ wa lojoojumọ pẹlu ojo to n rọ le wa lori yii, Abẹnugan, ẹ wa nkan ṣe si ki ọrọ to bẹyin yọ.”

Abẹnugan Ile Aṣofin nigba, Femi Gbajabiamila lasiko to n fesi si ọrọ naa ni ohun ti wọn gbọdọ mu ni ọkunkundun ni adari ọmọ ile aṣofin to kerejulọ sọ.

Igba akọkọ kọ ni yii ti Ile Igbimọ Asofin ti ma n jo loore-koore paapaa nigba ti ojo ba rọ, gbogbo agbegbe naa ni yoo kun fọfọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ