Mo ra epo bẹntiró ní N250, N300 ní ilé epo nítorí ọ̀wọ́ngógó bẹ́ntiró – Aráàlú fárígá!

Aworan

Awọn ọmọ Naijiria ti fi aidunnu wọn han si iṣoro ti wọn n la kọja nitori ọwọngogo epo bẹntiro kaakiri orilẹede Naijiria.

Pupọ ninu awọn to ba BBC sọrọ ni inira ati ọwọngogo ni aisi epo bẹnitirol naa jẹ fun wọn.

Eyi mu ki ọpọlọpọ eniyan maa ra ni ọwọngogo bii lati bii igba naira si ọọdunrun naira fun jaala epo kan.

‘’O kere tan wakati mẹfa ni a n lo lori ila ki a to ri epo ra ni ọwọngogo’’

Aworan

Bakan naa ni awọn eniyan sọ iriri wọn ni ilọrin, Ikirun, Ondo, Abuja, Eko ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lara awọn to ba BBC sọrọ ni oun ti wa lori ila fun bii wakati mẹfa ti oun ko si ri epo ra lẹyin ni arakunrin Joshua wa ra a sinu kẹẹgi ni N250 naira.

Ẹlọmiran, alagba John to sọ iriri rẹ ni N290 naira ni oun ra jaala epo kan ni ilu Ibadan.

Aworan

Awọn ọmọ Naijiria to ba wa sọrọ ni iriri wọn ni ilu ilọrin, Ikirun, Ondo, Abuja, Eko ati bẹẹ bẹẹ lọ ko dẹrun rara, eleyii ti wọn ni ohun kọ wọn lominu nipa orilẹede Naijiria.

Awọn miran bu ẹnu atẹ lu awọn oloṣelu ti ko naani iṣoro ti awọn araalu n la kọja ati inira to n de ba wọn.

Ẹlomiran ti lẹ ni lati Oṣu kẹta ọdun yii ni wọn ti n koju ọwọngogo epo bẹntiro ni ilu Abuja, ti wọn si n ra ni iye owo 250 si 300.

Aworan
Aworan

Amọ ninu gbogbo hila-hilo yii, niṣe ni awọn ọmọ Naijiria n gbadura fun awọn ileepo kọọkan ti wọn n ta jaala epo ni N180 naira kaakiri orilẹede Naijiria.

Wọn ni ọpọ igba ni awọn ileepo ọhun ki n fikun un epo bi awọn miran ṣe n ṣe, ti wọn si mu ayedẹrun fun awọn eniyan.

Aworan

Ijọba orilẹede Naijiria ti kede idi ti ọwọngogo epo fi gbode kan.

Minista fun ọrọ epo bẹntiro ni Naijiria, Timipre Sylva  lo fi iroyin naa lede lasiko to n ba BBC Pidgin sọrọ lowo ọwọngogo epo bẹnitirol to n waye kaakiri orilẹede Naijiria.

Sylva ni awọn to n ta epo yii n lọ ọrọ omiyale agbara ya ṣọọbu lati fi da ọwọngogo epo bẹntiro silẹ.

Owọngogo epo ọhun mu ki awọn ọlọkọ gba gbogbo oju ọna, eyi to tun n fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ loju popo.

Ìdí tí ọ̀wọ́ngógó epo fí wà ní Naijiria nìyíí…

Aworan

‘’O ṣẹni laanu pe awọn eniyan lo n fa ọwọngogo yii’’

Minisita naa ni lootọ ni ọjọ rọ ni Lọkọja, ti omi si pọ ni ọna ti ko si si ọkọ nla kankan to le kọja ayafi ki wọn gba ọna miran.

‘’Pupọ ninu wọn n gba ọna miran amọ wọn n gbe epo pamọ.’’

Ohun ti wọn n ṣe ni pe wọn n gbe epo pamọ ki awọn eniyan le san owo pupo lati ri epo ra.

Lati bi oṣu kan ṣẹyin ni awọn ilu ni Naijiria ti n koju aisi epo ati ọwọngogo epo bẹntirol

Bakan naa ni Minisita naa fikun un pe ti awọn ba gbe igbeṣẹ tako awọn to n ta epo naa yoo tun buru ju ti tẹlẹ lọ.

Minisita naa wa rọ awọn eniyan lati fi iye denu pe yoo dopin laipẹ.