Bàbá mi Alafin Oyo fẹ́ràn ipa tí mo kó nínú Sinimá Anikulapo, wọ́n sì fẹ́ wò ó àmọ́… – Adedoja Alaafin

Ọkan lara awọn ọmọbinrin Alaafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi Kẹta, Adedoja Adeyemi gbalejo BBC Yoruba to si sọ bi ibaṣepọ laarin oun ati baba rẹ ṣe dan to.

Adedoja ṣipaya eyi lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba to ti n ṣalaye iru baba ti Alaafin jẹ si gbogbo ọmọ rẹ.

Adedoja sọrọ nipa awọn nnkan to maa n wu u lati gbe ṣe ati bo ṣe ri anfani lati ṣe aṣeyọri ninu wọn.

Adedoja Adeyemi

Adedoja ni ko si ohunkohun ti ọmọ Alaafin kankan fẹ ṣe, baba yoo gba awọn nimọran lati kawe na tori Alaafin fẹran iwe gan.

Bo ṣe n kawe ti ipele ikẹkọgboye akọkọ ati ikeji naa lo n ṣe awọn nnkan mii pọ bii yiyan bii ologun ati pe o ti nifẹ si ere sinima gan.

Bi Adedoja ṣe rin pade gbajugbaja oṣere ati oludari ere, Kunle Anikulapo to si kopa ninu fiimu naa jẹ pataki sii.

Adedoja Adeyemi

“Igba ti mo sọ fun iya mi ati baba mi nipa ere Anikulapo, inu wọn dun sii gan pe ere nipa aṣa ni.

Koda, baba ti ni awọn maa wa wo bi a ṣe n ṣe ere naa lọ tabi ti a ba ti gbe e jade, amọ bo ṣe wu Ọlọrun lo n ṣe ọla rẹ.”

Adedoja n sọ eyi nipa bi baba rẹ, Alaafin ṣe jẹ ipe Ọlọrun ti ko si lanfani lati wo ipele igbesẹ mii ti oun gbe laye.

Adedoja Adeyemi

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí