Mó kópa nínú fíímù fún ọjọ́ mẹ́wàá, mo gba ₦1,000 – Lateef Adedimeji

Lattef Adedimeji

Oríṣun àwòrán, Instagram/Lateef Adedimeji

Gbajugbaja oṣere Nollywood, Lateef Adedimeji ti ni oun ti fi igba kan kopa ninu fiimu fun ọjọ mẹwa ti wọn si san ẹgbẹrun naira fun oun.

Adedimeji sọ eyi lasiko to n sọ iriri rẹ ni agbo oṣere ati bi o ṣe bẹrẹ lati inu ẹrọfọ ki o to di ilumọọka.

O ni ọdun marundinlogun ṣẹyin ni oun ti darapọ mọ Nollywood lorilẹede Naijiria, to si ti kopa ninu fiimu to le ni ọgrun laarin asiko yii.

Adedimeji to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji ni gbogbo ọna ni oun fi n dupẹ nitori ohun gbogbo ti oun la kọja, ayọ lo ja si fun oun.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”JSS 2 ni mo ti bẹrẹ si ni kopa ninu ere itage gẹgẹ bi oṣere”

”JSS 2 ni mo wa nigba ti mo bẹrẹ si ni ṣere pẹlu ajọ kan ti kii ṣe tii ijọba, Community Life Project (CLP) ni agbegbe Isolo nilu Eko lasiko ti wọn n ṣe ilanilọyẹ fun awọn eniyan nipa arun HIV/STDS ati awọn arun miran.”

”Awọn Ajọ CLP yii maa n lọ si awọn ileewe ti wọn si mu awọn to yanju julọ, ti wọn a si kọ wọn ni ilanilọyẹ nipa lilo ijo jijo, orin ati ere ṣisẹ lati fi polongo awọn ijamba to wa ninu arun wọn yii”

”Bi mo ṣe bẹrẹ iṣẹ oṣere niyẹn ti mo si wa pẹlu wọn fun ọdun meje, ko to di pe mo lọ si ileewe giga.”

”Mi o kọ nipa ere ṣiṣe ni ileewe, ohun ti mo lọ kọ ni fasiti ni imọ ibaraẹnisọrọ lawujọ, Mass Communication, ti mọ si gba iwe ẹri ni imọ Public Relation and Broadcast ni fasiti Olabisi Onabanjo, ni ipinlẹ Ogun.”

”Lẹyin naa mo ṣiṣẹ ni ileeṣẹ amohunmaworan kan ki n to fi iṣẹ naa silẹ nitori iṣe oṣere.”

Ninu ọrọ rẹ, gbajugbaja oṣere naa ni o wu oun lati ṣe iṣẹ agbẹjọro amọ oun ri pe ti oun ba ti sọ ọrọ awọn eniyan ma n rẹrin, nitori naa ni oun ṣe darapọ mọ ẹgbẹ oṣere.

Adedimeji ni ipa ti oun ko ninu fiimu to tii le julọ ni Ayinla, ti oun si kọ ọpọlọpọ ọgbọn nibẹ, debi pe kii ṣe gbogbo ọrọ bii eebu ti eniyan ba sọ si ilumọọka, ni yoo da pada tabi sọ da ibinu.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki lo wa laarin Lateef Adedimeji ati Mo’Bimpe?

Adedimeji, nigba to n fesi si ibeere pe ki lo wa laarin oun ati oṣerebinrin Mo’Bimpe ati iroyin pe lọkọ-laya ni wọn, ni ọrọ ẹyin lasan ti awọn eniyan n gbe kiri ni iroyin naa.

”Mi o ti gbe iyawo kankan, mo ṣi wa lakọ, amọ laipẹ ni ma a di baale ile.”

”Ko si oun to buru lati fẹ oṣere bii temi amọ ọrọ wa gbọdọ ye ara wa, ki a si ni ifẹ ara wa ni tootọ.”

”Bi o tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ obinrin ni o ma n yi mi ka ni igba gbogbo, mi o ba ara mi jẹ nitori o pọn dandan lati ṣọ ara ẹni ni awujọ awọn obinrin.”

Lateef Adedimeji wa gba awọn ọdọ ati awọn oṣere to n bọ lẹyin ni imọran wi pe, ohun ti wọn n ṣe gbọdọ da wọn loju nitori igba ti ipenija ba de, wọn a le duro ṣinṣin lati bori gbogbo ohun ti wọn ba la kọja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ