Buhari, káàbọ̀ sí Amẹ́ríkà àmọ́ ohun tà ń fẹ́ rèé – Yoruba Nation

Aworan aarẹ Buhari ati awọn to mu asia Yoruba Nation lọwọ

Awọn to n beere fun idasilẹ orileede Yoruba ti fi ọrọ ranṣẹ si aarẹ Muhammadu Buhari lori nkan tawọn fẹ ko yẹwo ṣaaju iwọde wọn ni ajọ isọkan agbaye United Nations, UN.

Wọn tun ni awọn yoo ṣe iwọde itagbangba niwaju ajọ UN lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹsan, ti ipade ajọ naa yoo waye.

Ọjọ yii kan naa ni aarẹ Buhari yoo sọrọ niwaju igbimọ apapọ ajọ UN.

Lọjọ Aiku ni aarẹ Buhari gbera kuro ni Abuja lọ si New York lati kopa ninu ipade apapọ ẹlẹẹkẹrinlelaadọrin ajọ naa.

Agbẹnusọ fawọn ajijagbara naa, to wa ninu ẹgbẹ Ilana Omo Oodua, Maxwell Adeleye ninu atẹjade to fi sita ka awọn nkan mẹfa, ti wọn lawọn n fẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Koko ohun mẹfa ti ikọ Yoruba Nation n beere lọwọ Buhari:

  • Ki Buhari wọgile iwe ofin Naijiria ọdun 1999.
  • Buhari gbọdọ so eto idibo rọ paapa idibo ọdun 2023 to n bọ lọna.
  • Buhari gbọdọ se agbekalẹ eto idibo lati fi mọ ero araalu boya wọn fẹ duro si Naijiria tabi bẹẹ kọ ta mọ si Refrendum
  • Ki wọn mu opin ba ipaniyan lati ọwọ awọn Fulani
  • Mimu opin ba jijẹ gaba le awọn araalu lori ati
  • Kikede ẹgbẹ Miyetti Allah gẹgẹ bi ẹgbẹ agbesunmọmi

Atẹjade naa tun sọ pe alaga agbarijọpọ awọn ẹgbẹ to n beere fun idasilẹ Yoruba Nation, Ọjọgbọn Banji Akitoye ni ”kaka ki ijọba Buhari tẹti gbọ ohun t’araalu fẹ, niṣe lo n doju ija kọ awọn to fẹ dẹkun ikọlu lati ọwọ awọn darandaran Miyetti Allah”

”Ipe wa si ijọba ni ki wọn wo atẹjade ti NINAS gbe jade lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kejila ọdun 2020. Ipe yii ṣe pataki ki awọn ẹya to wa labẹ NINAS le dunadura nnkan ti wọn fẹ lai si idiwọ”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O fi kun pe ohun tawọn fẹ ni ki ijọba ”ṣeto idibo ti araalu yoo ti sọ ohun ti wọn fẹ, referendum, ki awọn to wa lati iwọ guusu ati aarin gbungbun Naijiria yoo le gbe igbesẹ iṣejọba ara wọn.

A n beere fun ki wọn wọgile iwe ofin Naijiria ọdun 1999 ni kiakia”

”A o tun bẹrẹ iwọde wa lọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kẹsan niwaju ileeṣẹ ajọ UN lati le sọ fun aarẹ Buhari pe, awọn Miyetti Allah rẹ ni ọta awọn eeyan aarin gbungbun Naijiria ati iwọ oorun guusu Naijiria.

Awọn gangan ni agbesunmọmi”

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: