Ẹ wo bí àwọn ọmọ Naijiria mẹ́ta ṣe fí ẹ̀mí wọn wéwu láti rin ìrínàjò lọ sí Spain

Aworan

Oríṣun àwòrán, SPANISH COASTGUARD

Ẹṣọ alaabo lorilẹede Spain ni awọn ti ri awọn arinrinajo mẹta kan lori irin ọkọ oju omi lẹyin irinajo ọjọ mọkanla lati Naijiria lọ si Spain.

Aworan kan ti wọn fi lede ṣafihan bi awọn ọkunrin naa ṣe joko si ori irin ti wọn n gbe epo si ninu ọkọ oju omi agbepo ọhun, ti ẹṣẹ wọn si ku diẹ ki o kan omi.

Lẹyin naa ni wọn gbe wọn lọ si ileewosan fun itọju aini omi lara tọ bo ṣe yẹ.

Ko han si gbangba boya ọjọ mọkanla naa ni wọn fi wa ni ori irin ti wọn joko le bi aworan ṣe gbe e jade.

Ọkọ oju omi Di Maltese-flagged Althini II na lo de si Las Palmas, Gran Canaria, lẹyin to gbera kuro ni ilu Eko, lorilẹede Naijiria.

Irinajo naa ni iwadii fihan pe o ju ẹgbẹrun meji maili lọ ni ori omi.

Awọn dokita to doola ẹmi wọn ri wọn nibi ti wọn ha si ni abẹ ọkọ oju omi naa ti wọn si gbe wọn lọ si ileewosan.

Dandan awọn arinrinajo naa gbọdọ pada si ile- Ijọba Spain

Aworan

Oríṣun àwòrán, SPANISH COASTGUARD

Amọ ẹṣọ alaabo lorilẹede Sdpain ti ni dandan awọn arinrinajo naa gbọdọ pada wale.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nibẹ ni labẹ ofin arinrinajo to ba rin iru irinajo to le wu bayii gbọdọ pada si ile.

Ninu foto ti wọn fi si oju opo ikansiraẹni Twitter wọn ni wọn ti kede rẹ.

Wọn ni ohun ti awakọ oju omi naa yoo ṣe ni lati tọju awọn wọnyii nipa pipese ile gbigbe fun wọn fun igba diẹ, ti yoo si da wọn pada si ile.

Amọ adari ileeṣẹ arinrinajo ti ki n ṣe ti ijọba ni awọn mẹta naa le duro si orilẹede Spain ti wọn ba ni ẹri to daju pe awọn kan n dunkoko mọ wọn, ki wọn si gba aṣẹ lati di atipo ki wọn lee wa ni orilẹede na.