Láì sí ẹ̀kùn àríwá, òfo ní ìpínlẹ̀ Eko, Rivers lórí owó ọjà – Masari

Aworan nipa owo ori ọja

Oríṣun àwòrán, InvestSmall

Ọrọ ti n ba ọrọ bọ lori ipinnu awọn gomina meji lẹkun guusu Naijiria ti wọn pinnu lati maa gba owo ori ọja sapo ara wsn lai fi ransẹ sọdọ ijọba apapọ.

Awọn ipinlẹ naa ni ipinlẹ Eko ati Rivers ti wọn kede pe iyanjẹ ti pọ ju lori bi ijọba apapọ se n pin owo ori ọja tawọn n pa wọle fun.

Amọ gomina ipinlẹ Katsina, Bello Masari ti wa fesi pada fawọn gomina mejeeji naa pe ofo ọjọ keji ọja ni igbesẹ wọn naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Masari ni agbajọ ọwọ la fi n sọya ni ọrọ owo ori ọja, laisi awọn ipinlẹ yoku tabi ẹkun ariwa tawọn naa n gbe owo ori ọja kalẹ, owo ti wsn n pin fun ipinlẹ Eko ati Rivers ko ni jẹ gọbọi.

O wa se apejuwe igbesẹ awọn gomina Eko ati Rivers naa bii awada lasan nitori awọn eeyan lati awọn ipinlẹ miran ni wsn gbara le lati se agbega eto ọrọ aje wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Ki ni ipinlẹ Eko ja mọ lai si awọn ipinlẹ yoku ni Naijiria? Awọn ọja ti ipinlẹ Eko n mu yangan yii lo gbara le gbogbo eeyan lati awọn agbegbe mii yika Naijiria.

Se bi orilẹede Benin ati Togo naa ni ibudokọ oju omi, se wọn ni eeyan to to lati ri owo ribiribi gba lawọn ibudokọ oju omi naa?

Lai si awọn eeyan to n lo awọn ibudokọ oju omi yii yika Naijiria, ki ni ipinlẹ Eko yoo ja mọ?”

Masari fikun pe bi owo ori ọja yii se wulo fun Eko ati Rivers, naa lo wulo fun awọn ipinlẹ yoku naa, awọn si lo n pese ọja fun wọn nitori lai si awọn ipinlẹ yoku ni Naijiria, nibo ni Eko ati Rivers yoo wa?

O fikun pe ipinlẹ kipinlẹ to ba ro pe oun le da duro lai si iranwọ awọn ipinlẹ yoku n se awada akọ ni nitori awọn lo n pese eroja to n mu ki Eko di ohun to da lonii.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bẹẹ ba gbagbe, awọn gomina yoku ni guusu Naijiria naa ti n se atilẹyin fun ipinnu ipinlẹ Eko ati Rivers lati maa gba owo ori ọja ti wọn ba pese nipinlẹ koowa wọn.

Koda, ọrọ yii si ti wa niwaju ile ẹjọ Kotẹmilọrun ati ile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn agbẹ́bọn tí pa alága ẹgbẹ́ Miyetti Allah tí wọ́n jígbé ní Kaduna- Miyetti Allah

Miyetti Allah

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ awọn darandaran lorilẹede Naijiria, MACBAN ti kede iku Allhaji Abubakar Abdullahi to jẹ alaga ẹgbẹ ni agbegbe Danbardi ni ipinlẹ Kaduna.

Ẹgbẹ Miyetti Allah kede iku rẹ ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa, Othman Ngelzarma fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Miyetti Allah ni ẹni ọdun mejidinlọgọta ni alaga naa ki awọn agbebọn to ṣekupa a.

”O ti jẹ eniyan marun un ninu ẹgbẹ Miyetti Allah ti awọn agbebọn, ajinigbe ati awọn darandaran ti pa kaakiri orilẹede Naijiria”

”Ẹgbẹ orita ni titi ni wọn ti ri oku Abdullahi lẹyin ti wọn jigbe ni ile rẹ ni Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Kẹsan, ọdun 2021.”

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Lẹyin ti wọn san owo ẹmi alaga naa ni awọn ajinigbe naa sọ ara rẹ si ẹgbẹ titi ni agbegbe ilu Lere.”

Ẹgbẹ Miyetti Allah wa kesi awọn ẹṣọ alaabo lati ri pe wọn ṣe iwadii iku yii, ki wọn si fi awọn to ṣiṣẹ ibi yii jofin.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan naa ni wọn ni kegbare lori eto aabo to dẹnukọlẹ kaakiri orilẹede Naijiria, ti ko si yọ awọn silẹ.

”Ti eleyii ba tẹsiwaju o ṣeeṣe ki o fa idiwọ fun ẹka iṣowo ẹran tita kaakiri Naijiria”

Ẹgbẹ Miyetti Allah wa rọ ijọba apapọ lati gbe awọn eto kalẹ ti yoo mu ki irọrun ba eto iṣẹ ọsin ẹran ni Naijiria.