Ní Unilorin, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wọ aṣọ tí kò tọ́ ṣán oko, fọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀

UNILORIN

Oríṣun àwòrán, bbc

Fasiti ijọba apapọ to wa niluu Ilọrin, Unilorin, ti pàṣẹ kawọn akẹkọọ kan fọ ile igbọnsẹ nile ẹkọ naa latari pe wọn mura lọna to lodi si ofin ile ẹkọ ọhun.

Iṣẹlẹ naa lo waye lọjọ Aje, ọjọ kẹfa, oṣu Karun un yii ninu ọgba ile ẹkọ giga naa.

Ninu ọrọ rẹ akọwe agba fasiti naa, Mansur Alfanla, o ni awọn ko faramọ iwa ibajẹ lo jẹ ki wọn da seria fun awọn akẹkọọ to ru ofin aṣọ wiwọ wọn.

Gẹgẹ bo ṣe wi, Unilorin ni ofin to de imura lọna aitọ.

Akọwe agba naa fikun ọrọ rẹ pe kii ṣe ẹkọ iwe nikan lawọn n kọ awọn akekọọ wọn tun n kọ wọn nipa iwa ọmọluabi pẹlu.

O ṣalaye pe awokọse Unilorin ati awọn akekọọ rẹ jẹ fun gbogbo Naijiria, ati pe ofin to de mimura lọna aitọ si ti wa tipẹ.

Lasiko ti akọroyin BBC Yoruba n fi ọrọ wa awọn akekọọ lẹnu wo, omidan Basirat Jimoh ni lati ọjọ Jimọh to kọja ni igbesẹ naa ti bẹrẹ.

Lara awọn akekọọ ti wọn mu ni awọn ọkunrin to lo yẹti, awọn to gẹrun ti ko bojumu, awọn obirin to wọ aṣọ to ṣi ara silẹ, awọn obirin ti ko se irun wọn dáadáa ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu ọrọ rẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, alukoro ile ọhun, ọgbẹni Kunle Akogun sọ pe o ti to ọdun mẹrin ti ile ẹkọ naa ti gbe iru igbesẹ bẹẹ kẹyin, amọ ofin wa to si mulẹ gidi.

O fikun pe ijiya ti wọn fun awọn ti wọn mu ni ṣiṣan oko, fifọ ile igbọnsẹ, mimu wọn yika ọgba ile ẹkọ pẹlu alaye pe wọn fi eleyi fa wọn leti ati bẹẹ bẹẹ lọ.