Aráàlú dín dùndú ìyà fún òṣìṣẹ́ FRSC lẹ́yìn tí wọ́n ní ó ṣokùnfà ìjàmbá ọkọ̀ n’Ibadan

FRSC Oyo

Oríṣun àwòrán, @DailyPostNGR

Awọn araalu kan ti rọ ojo iya le oṣiṣẹ FRSC kan lori lagbegbe Oke Bola, niluu Ibadan lori ẹsun pe oun atawọn akẹgbẹ rẹ lo ṣokunfa ijamba ọkọ kan nibẹ.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ, a gbọ pe awọn oṣiṣẹ FRSC naa lọwọ ninu ijamba ‘hit-and-run’ kan.

Fidio kan tawọn eeyan n pin lori ayelujara ṣafihan bi awọn eeyan ṣe di oju ọna mọ awọn ẹṣo oju popo naa.

Skip Twitter post

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Gẹgẹ bo ṣe waye ninu fidio ọhun, ṣe ni awakọ awọn oṣiṣe FRSAC naa fi ọkọ wọn silẹ to si sa asala fun ẹmi ara rẹ.

Bi dẹrẹba naa ṣe n salọ lawọn araalu n le bii ole to ja pọọsi gba ninu ọja.

Amọ ọkan lara awọn oṣiṣẹ FRSC naa to fo oju titi lọ si odikeji tun ko sọwọ awọn araalu ti wọn si bẹrẹ si n dawọ iya jọ fun.

A gbọ pe ni kete ti awọn ọlọpaa to maa n ṣe ayẹwọ ọkọ lagbegbe naa ri ohun to n ṣẹlẹ lawọn naa ba ẹsẹ wọn sọrọ.

Oṣojumikoro kan to n ṣiṣẹ nile epo to wa lẹba ibi iṣẹlẹ naa ti waye sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle Vangard pe ibinu ijamba naa lawọn araalu fi mọ awọn oṣiṣẹ FRSC ọhun.

Wayi o, ajọ FRSC ko tii sọ nnkankan nipa iṣẹlẹ naa ati ipa ti awọn oṣiṣẹ rẹ ko ninu ijamba ọhun.