Tinubu là ń dúró dè láti sọ ìpinnu wa fétò ìṣèlú 2023 – Akeredolu

Akeredolu ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti ni awọn n duro de adari lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ko de lati oke okun, ko le wa sọrọ lori erongba rẹ fun idibo sipo aarẹ ni ọdun 2023.

Akeredolu, to jẹ Alaga Ajọ awọn Gomina ni Guusu Naijiria lo sọ bẹẹ lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin, Arise TV.

Ninu ọrọ rẹ, Akeredolu ni awọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni Guusu Naijiria n duro de Tinubu ko de lati oke okun to ti lọ gba itọju, ki awọn le mọ ibi ti wọn n lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gomina Akeredolu ni oun ko ṣetan lati kuro ni ẹgbẹ oṣelu APC nitori ibẹ ni oun yan laayo, ti oun si ti sọ fun awọn eniyan ni ọpọ igba.

Bakan naa lo fikun pe, idi iṣẹ agbẹjọro ti oun yan laayo lati ibẹrẹ aye oun ni oun yoo pada si lẹyin ti oun ba pari saa keji gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ondo.

Akeredolu, Fayemi ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Nitori naa, Alaga Ajọ awọn gomina ni guusu Naijiria naa ni ẹnikẹni ti ẹgbẹ oṣelu APC ba ti fa silẹ lati dije dupo aarẹ, ni oun yoo ṣe atilẹyin fun.

Akeredolu fikun pe Bola Tinubu ṣi ni adari awọn ni Guusu Naijiria, nitori naa, oun to ba sọ ni awọn yoo tẹle.

Ọpọlọpọ igun lo ti dide lati fi atilẹyin wọn han fun Tinubu saaju idibo si ipo aarẹ ni ọdun 2023.

Amọ Tinubu to n gba itọju lọwọ ni ilu London lẹyin ti wọn ṣe iṣẹ abẹ fun un ko i tii sọrọ boya lootọ ni yoo dije dupo fun aarẹ ni ọdun 2023.

Osu to kọja ni Gomina Akeredolu ati Gomina ipinlẹ Ekiti,. Kayode Fayemi, ṣe abẹwọ si Tinubu ti wọn si jọ ṣe ipade pọ, amọ ko i tii si abajade ipade wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ