Yèyé Osun, babaláwo àti alfa tó ń ṣe alápatà ẹran èèyàn kó sí gbaga ọlọ́pàá

Aworan ẹni to wa ni gbaga ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fọwọ ṣinkun ofin mu awọn eeyan kan ti wọn fẹsun kan wi pe wọn n ṣekupa awọn eeyan ti wọn ṣi n ta ẹya ara wọn fun owo.

Awọn afurasi ti wọn mu naa ni Yeye Osun, babalawo, alfa, oloye adugbo kan ati oniṣegun ibilẹ kan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, ṣalaye pe nipa iṣẹ iwadii ati iranlọwọ araalu lawọn fi ri awọn afurasi naa mu.

Ademola Akinlosotu to jẹ olori awọn afurasi naa ni alukoro ọlọpaa ni o jẹwọ pe niṣe loun maa n hu oku awọn eeyan kaakiri ibi-isinku ti oun yoo si ta ẹya ara wọn fawọn to n ṣe oogun owo.

Hundeyin ni Akinlosotu ẹni ọdun mẹtalelọgbọn tun jẹwọ pe nigba to ya ni oun bẹrẹ si ni pa eeyan ti oun ṣi n ta ẹya ara wọn fawọn onibara oun.

Akinlosotu ṣalaye pe ọkunrin kan to jẹ Ahmed Wahab ti inagijẹ rẹ n jẹ Alfa Bororo lawọn maa n ta ẹya ara awọn eeyan tawọn ba ti pa fun.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni afurasi yii fidi rẹ mulẹ pe owo to to N45,000 si N50,000 lawọn maa n ta ori eeyan, amọ, ori gbigbẹ ko ju bi N30,000 ati N35,000 lọ.

Akinlosotu jẹwọ pe oun pa eeyan meji eyi ti ọrẹ oun kan toun pade lori ayelujara wa ninu wọn ki ọwọ ọlọpaa to ba oun.

Afurasi naa ṣalaye pe ki awọn to pa ẹnikẹni, awọn maa n kọkọ beere lọwọ babalawo awọn lati da Ifa ki wọn le mọ bo ya ẹni to yẹ ki wọn pa ni tabi ẹni to le mu wahala wa.

Akinlosotu tun fikun ọrọ rẹ pe ọba alaye kan bẹ oun lati ṣekupa ọkan ninu awọn ọmọ rẹ tori o n fun un ni wahala.

O ni ọjọ tawọn fẹ lọ pa ọmọ naa ni ọrẹ oun tawọn pade lori ayelijara ṣe abẹwo soun ti oun ṣi pa a.

Hundeyin ni oriṣiiriṣii ẹya ara eeyan ni ileeṣẹ ọlọpaa ri gba lọwọ awọn afurasi naa.

O ni awọn afurasi yii yoo foju ba ile ẹjọ laipẹ.