Ilé alájà márùn ún dàwó, gbẹ̀mí èèyàn mẹ́rin

Aworan awoku ile naa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Iṣẹ idoola ẹmi n tẹsiwaju lorilẹede South Africa lẹyin ti ile alaja marun un kan ti wọn n kọ lọwọ dawo to si pa eeyan mẹrin loju ẹsẹ.

Awọn alaṣẹ ni ilu George nibi ti ajalu naa ti ṣẹlẹ lẹkun Western Cape ṣalaye pe eeyan ti ko din ni aadọta ni wọn ha si abẹ awoku ile naa, wọn si ti fa awọn mẹrinlelogun jade labẹ awoku ile naa ti wọn si ti gbe wọn lọ si ile iwosan.

Ko tii si ẹni to le sọ ohun to ṣokunfa bi ile naa ṣe dawo, amọṣa awọn alaṣẹ nibẹ n sọ pe iwadi n lọ lọwọ lori rẹ.

Nnkan bii agogo meji ọsan kọja iṣẹju diẹ ni South Africa eyi to bọ si nnkan bi agogo mejila GMT(12: 09 GMT).

Meji ninu awọn mejilelogun ti wọn fa jade labẹ awoku orule naa lo jade laye nitori ọgbẹ ti wọn gba sara. Lẹyin eyi ni awọn meji miran tun jade laye.

Alaṣẹ ẹkun Western Cape, Alan Winde ṣalaye pe “Oṣiṣẹ marundinlọgọrin lo wa lẹnu iṣẹ lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.”

Olotu ilu George, Ald Van Wyk pẹlu kẹdun pẹlawọn to farakaaṣa ajalu naa.