Jíjẹ́ obìnrin ti ṣí ọ̀pọ̀lọ̀pọ̀ ọ̀nà fún mi, ẹ̀yin obìnrin ẹlẹgbẹ́ mi ẹ wá kọ́ bẹ́ẹ ṣe lè lo kíní yín – Bobrisky

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, WithChude

Gbajugbaja ọkunrin to maa n mura bi obinrin, Idris Okuneye ti ọpọ mọ si Bobrisky ti ni bi oun ṣe jẹ obinrin lọwọlọwọ yii, oun n gbadun rẹ gidi gan to si ti lana pupọ fun un.

Bobrisky n sọ eyi lori eto gbajugbaja afọrọwanilẹnuwo, Chude lori eto #WithChude nibi to ti n sọ pe awọn obinrin n sọ anfani nla nu pẹlu bi wọn ko ṣe ki n lo nkan ti Ọlọrun fun wọn daadaa.

O jẹ igba akọkọ ti Bobrisky yoo farahan lori ẹrọ amohunmaworan lọdun 2021 to tun jẹ ọdun kan naa to ṣe ayẹyẹ nla fun ọjọ ibi ọgbọn ọdun rẹ.

Nigba to bii pe “Ọkunrin ni wọn bi ẹ, ki lo de too fẹ parada di obinrin”, Bobrisky ni:

“Tori jijẹ obinrin bayii ti ṣi ọpọlọpọ ọna fun mi. Awọn obinrin o tilẹ mọ bi wọn ṣe lagbara to, ọpọ wọn ko mọ bi wọ́n ṣe le lo ẹbun ti wọn ni gẹgẹ bii obinrin”.

O ni nigba ti oun ṣi jẹ́ ọkunrin, ko sowo, ko tilẹ sẹni to maa n da si oun, to fẹ ba oun ṣe tori ai si owo. “Mo kan n “hustle ni”.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bobrisky ni igba naa loun pinu pe oun ko fẹ iru nkan bayii, oun fẹ jẹ ọga ara oun.

Ni ti awọn kan koda lara awọn to n tẹlee lori ayelujara ni o n ja awọn kulẹ pẹlu bo ṣe n ṣe, Bobrisky ni “haa, ki wọn ma roo bẹẹ́ o, ki wọn ma wo mi, ẹyin naa ẹ gbe tiyin jade”.

Idris ni oun sunmọ iya to bi oun daadaa ko to di oloogbe. “Eeyan kan ṣoṣo to nifẹ mi niyẹn to gbaruku ti mi nigba ti gbogbo eeyan kọ mi silẹ”.

O ni bo tilẹ jẹ pe baba oun gan kọkọ woo pe, ohun to yẹ koun maa ‘ṣe kọ leleyii, oun tawọn jọ sọ kọ yii o pada gbaruku ti oun.

“Owo ni gbogbo nkan o. Too ba n sọ pe owo kọ ni gbogbo nkan, o n parọ tan ara rẹ jẹ ni. Ṣe ti Buhari o ba jẹ aarẹ, o lee mọọ ni gbajumọ?”. O ni too ba fẹ orukọ rere, pẹlu owo ni.

Bawo ni Bobrisky ṣe di eeyan to ni ọyàn?

Bobrisky ni ori ayelujara ni gbogbo nkan wa bayii oun ko si fẹ sọrọ nipa rẹ.

O ni oun ṣaa fẹ jẹ ọga ara oun ti oun si fẹ lo nkan toun ni fi ri nkan ti oun fẹ gba lai ro ohun ti ẹnikni n sọ tori ohun to ba wu ẹlẹnu lo le fi ẹnu rẹ sọ.