Jagaban Army fẹ́ da Naijiria rú ni, ọ̀rọ̀ Tinubu ń fẹ́ ìfura – Atiku

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, @atiku

Ikọ ipolongo oludije sipo Arẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, ti ni awọn to n ṣiṣẹ fun Bola Tinubu labẹ asia  Jagaban Army n jẹ ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria lẹsẹ.

Ikọ ipolongo naa si ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati lati pe ipade pajawiri pẹlu awọn ti eto abo kan lori ọrọ naa.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ikọ ipologno Atiku, Kola Ologbondiyan fi lede, o ni idasilẹ Jagaban Army naa n tumọ si pe Bola Tinubu fẹ fi tipa tikuku de ipo Aarẹ.

O ni “Awọn eeyan ti fẹsun ka kan ẹgbẹ Jagaban Army pe wọn n ṣe idanilẹkọ fun awọn janduku kan pẹlu nnkan ija oloro ninu igbo.

 Irọ  ni PDP n pa, ọrọ ko ri bi wọn ṣe n sọ – APC

Amọ adari awọn ọdọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Dayo Israel ti sọ pe irọ ni ẹsun naa, ati pe Jagaban Army ko wa fun idaluru, bi ko ṣe lati ṣiṣẹ takuntakun lati gbe Tinubu de ipo Aarẹ.

Ṣugbọn  PDP ti fesi pe awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun ran aṣọ bii Ologun, wọn si ni oye laarin ara wọn bii ti awọn ọmọ ogun, eyii to mu ifura lọwọ.

PDP sọ pe ilu London ni Tinubu ti ṣe ipade pẹlu awọn ẹmẹwa rẹ, to si paṣẹ fun wọn ki wọn ṣe gbogbo ohun to yẹ ki oun le de ipo Aarẹ.

Atẹjade naa ni “Ọrọ to sọ pe ipo oṣelu kii ṣe nnkan ti wọn n gbe fun eeyan nile ounjẹ… nnkan ti eeyan gbọdọ ja kitakita fun” tito lati fi ẹsun iditẹgbọjọba Tinubu.

Ologbodiyan sọ siwaju si pe oun ti Tinubu n ṣe mọọmọ n tẹ agbara Buhari loju mọlẹ ni.

O ni “Gbogbo ohun ti yoo gba ni Tinubu fẹ ṣe lati de ipo Aarẹ Naijiria, amọ ọpọ ọmọ Naijiria lo ti kọ ọ.”

Ologbondiyan pari ọrọ rẹ pe “Awọn oniruru ẹgbẹ to n da omi alaafia awọn orilẹ-ede ru kaakiri agbaye ko ṣẹyin awọm oloṣelu to fẹ fi ipa gba ipo oṣelu.”