NDLEA mú bàbá tójú ń dùn, ẹni ọdún 67 pẹ̀lú egbòogi olóró, gba kóró tramadol 1.6m l‘Eko  

NDLEA

Oríṣun àwòrán, NDLEA

Ajọ to n gbogun ti egboogi oloro ni Naijiria, NDLEA, ti gbẹsẹle oogun oloro cocaine atis skunk ti awọn eeyan kan gbe wọ Naijiria lati orilẹ-ede Brazil.

Bẹe naa ni wọn tun gbẹẹle oogun oloro tramadol ti iye owo rẹ din diẹ ni miliọnu meji naira niluu Eko.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Femi Babafemi fi lede, o ni papakọ ofurufu Akanu Ibiam International Airport, AIIA, to wa niluu Enugu ni ọwọ ti tẹ awọn to gbe cocaine ati skunk wọ Naijiria.

Nigba ti baba agba kan ti ko riran wa lara awọn ti ọwọ tẹ lori ẹsun gbigbe oogun oloro ni Osun, Kano, Ondo, Edo ati ilu Abuja.

Babafemi sọ pe ọkunrin kan to n bọ lati orilẹ-ede Brazil, Eze Christian Ikenna ni ọwọ tẹ niluu Enugu pẹlu awọn apo kan to sọ pe àgbo lo wa ninu rẹ, amọ nigba ti wọn yoo fi yẹ awọn apo naa wo, egboogi cocaine lo wa ninu rẹ.

O fi kun pe inu ile akẹru kan ni ibudokọ eti omi TIncan to wa niluu Eko ni ọwọ ti tẹ awọn to ko oogun oloro sinu awọn ayọkele Toyota Sienna ati Honda Pilot ti wọn ko wọle si Naijiria.

NDLEA

Oríṣun àwòrán, NDLEA

NDLE ṣawari ile ti wọn ko koro tramadol 1,645,560 si niluu Eko

Babafemi sọ siwaju si pe awọn ti ṣawari ile kan ni Greenfield estate, to wa ni Amuwo Odofin, niluu Eko, nibi ti awọn ti ri ẹgbẹlẹgbe koro tramadol ti awọn ti n tọpinpin fun ọjọ pipẹ.

Yatọ si ile yii, NDLEA tun ka koro tramadol 60,000 mọ inu ile mii lagbegbe Bariga.

Nipinlẹ Osun  NDLEA ṣawari ile ti wọn n ko igbo pamọ si ni abule Sokoto, to wa ni Owena Ijesa, ni ijọba ibilẹ ila oorun Atakumosa.

Gẹgẹ bii ohun ti NDLEA sọ, baba agba ẹni ọdun mẹtadinlaadọrin kan to tun jẹ afọju ni igbo ọhun wa ni ikawọ rẹ.

Ni ipinlẹ Ondo, NDLEA ṣawari ọọdunrun ati aadọrin kilo igbo lagbegbe Ilale, niluu Ọwọ.

Ni gba to n sọrọ loriawọn aṣeyọri naa, ọga agba NDLEA, Brig. Gen. Mohamed Buba Marwa gboriyin fun awọn oṣiṣẹ ajọ naa fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe.

O ni awọn ko ni dẹkun ojuṣe wọn lati fọ Naijiria mọ lọwọ oniruru egboogi ti ko ba ofin mu.