Ìwọ̀nba àsìkò tí mo lò ní àtìmọ́lé jẹ́ kí mọ pàtàkì òmìnira – Trinity Guy

Aworan Trinity guy

Oríṣun àwòrán, Trinity guy

Gbajumọ adẹrinpoṣonu lori ayelujara, Abdullahi Maruf Adisa ti ọpọ mọ si Trinity Guy ti salaye iriri rẹ ni iwọnba asiko to lo ni atimọle lẹyin ti ileẹjọ ni ko lọ ma rọkun lọgba ẹwọn.

Saaju ni Ile ẹjọ Majisireti to n gbọ ẹsun ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan alawada ajanilaya ori ayelujara, Trinity Guy, ti kọkọ ni ki wọn fi afurasi naa pamọ sọgba ẹwọn.

Lọjọ Kejilelogun oṣu to kọja ni Trinity Guy gba ìtusílẹ kuro ní ahamọ to wa.

Trinity ni iwọnba asiko ti oun lo ni ahamọ ti fihan oun pataki ominira ati bi oun se jina si awọn mọlẹbi se se oun ni ọpọlọpọ ijamba .

“Lilo asiko diẹ ni ahamọ ti jẹ ki n mọ pataki ominira ati ipa awọn mọlẹbi mi.

“Ma ri pe mo tẹsiwaju, n o si tun ri pe mo yago fun ohunkohun to lodi ofin

MAdẹrinpsṣonu naa ko tun ṣai dupẹ lọwọ gbogbo awọn ololufẹ, akẹgbẹ ati mọlẹbi rẹ, to si tun kan sara si ileeṣẹ ọlọpaa fun aduroti wọn lasiko to wa latimole.

Ìyanṣẹ́lódì NLC tún ṣàkóbá fún ‘Trinity Guy’ ní ilé ẹjọ́

Igbẹjọ gbajumọ adẹrinpoṣonu lori ayelujara, Abdullahi Maruf Adisa ti ọpọ mọ si Trinity Guy lo yẹ ko waye lonii sugbọn awọn alasẹ ileẹjọ ni ko ni le waye nitori awọn darapọ mọ iyansẹlodi.

Akọroyin BBC balẹ si ileẹjọ lowurọ oni lati bi igbẹjọ naa yoo se waye sugbọn awọn osisẹ ileẹjọ jẹ ko di mimọ pe iyansẹlodi n lọ lọwọ, ti igbẹjọ naa ko si ni waye.

A ko le sọ pato asiko ti igbẹjọ yoo waye bayii.

Trinity Guy yóò tún padà sí ilé ẹjọ́ lónìí

Gbajumọ adẹrinpoṣonu lori ayelujara, Abdullahi Maruf Adisa ti ọpọ mọ si Trinity Guy yoo tun foju ba ile ẹjọ lọjọbọ ọjọ kẹta oṣu kẹjọ ọdun 2023.

Trinity guy n jẹjọ ẹsun hihu iwa kotọ to nii ṣe pẹlu ọmọdẹbinrin ọmọ ọdun mẹwaa kan nilu Ibadan.

Nibi igbẹjọ ẹjọ naa to waye lọjọ kọkanlelogun oṣu keje ni ile ẹjọ to n gbọ ọrọ idile lagbegbe Iyaganku nilu Ibadan gba beeli Trinity guy lẹyin to ti lo ọsẹ mẹrin ni ahamọ ọgba ẹwọn Agodi.

Ni ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹfa ni gbajumọ adẹrinpoṣonu naa kọkọ foju ba ile ẹjọ lẹyin ti alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Olumuyiwa Adejọba ti kọkọ pe fun fifi kele ofin gbe e nitori awọn fọnran adayajani to n ṣe lori ayelujara.

Trinity Guy nikan kọ lo n foju ba ile ẹjọ lori ọrọ naa.

Awọn agbofinro gbe awọn obi ọmọdebinrin naa lẹyin ti adẹrinpoṣonu naa ṣalaye fun wọn pe pẹlu mimọsi awọn obi rẹ loun fi ṣe gbogbo ohun ti oun ṣe lọjọ naa.