Ìjàmbá ‘Elavator’ gba ẹ̀mí dókítà kan ní Ìpínlẹ̀ Eko

Aworan Vwaere Diaso

Oríṣun àwòrán, EDIDIONG IKPE

Ẹgbẹ awọn dokita lorilẹede Naijiria, NMA ti ke si ijọba lati bẹrẹ iwadi lori iku ọkan lara ọmọ ẹgbẹ wọn to ku ninu ijamba akasọ igbalode ‘Elevator’ lọjọ Isẹgun ọsẹ yii.

Dokita Vwaere Diaso jade lasiko ti ẹrọ akasọ igbalode ‘Elevator’ ọhun ja nigba to n lọ si ibi isẹ rẹ ni ile iwosan General hospital to wa nilu Odan nipinlẹ Eko.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe Diaso wa ninu akasọ igbalode ‘Elevator’ lasiko to ja lati aja kẹsan an silẹ, to si gba ẹmi rẹ.

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ naa fi sita, eyi ti alaga ẹgbẹ NMA nipinlẹ Eko, Dokita Benjamin Olowojẹbutu ati akọwe agba ẹgbẹ naa, Dokita Ismail Ajibowo salaye pe fun nnkan bii ogoji iṣẹju ni Diaso fi ha sinu akasọ igbalode naa lẹyin to ja lai ri iranlọwọ.

NMA ti wa pasẹ fun gbogbo awọn dokita to jẹ ọmọ ẹgbẹ naa lati gunle iyansẹlodi titi ijọba yoo fi bẹrẹ iwadi lori isẹlẹ naa.

Bakan naa ni ẹgbẹ NMA ni awọn eeyan to lọwọ ninu iku dokita naa ni wọn gbọdọ ri ijiya labẹ ofin

Edidiong Ikpe, ọrẹ timọtimọ Diaso to ba ileeṣẹ BBC News sọrọ salaye pe ọsẹ meji pere lo ku fun dokita naa lati pari ẹkọ imọkun imọ fun awọn dokita, eyi ti wn n pe ni ‘housemanship’ to wa kọ ni ile wosan naa.

“Eeyan dada ni ọrẹ mi, to ma n rẹrin ni gbogbo igba, ọlọyaya si ni pẹlu.”

Dokita agba fun ile wosan naa, Dokita Mafe Aduke ko ti sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

“A fẹ idajọ ododo”

Aworan awọn olufẹhonuhan

Awọn dokita ile wosan General ni Odan se ifẹhonuhan lori ijamba to waye si ọkan lara wọn to jade laye

Ọkan lara awọn olufẹhonuhan to ba ileeṣẹ BBC News sọrọ, Dokita Ajuwon Olumide ni awọn fẹ idajọ ododo fun eeyan wọn to lọ ati pe awọn alasẹ ile wosan naa gbọdọ gbe igbesẹ lati se atunse lori bi awọn nnkan yii n waye

Dokita Olumide ni oun gbiyanju lati lo ‘Elevator’ lati yara kẹfa lọ si yara kẹjọ lati lọ ri eeyan sugbọn oun ko le duro nitori yara akọkọ ni ‘Elevator’ ọhun si wa lasiko ti oun n gbera, ti oun si ni lati lo ẹsẹ oun lọ si ibẹ.

O ni nigba ti oun ma de ibi ti oun lọ ni oun gbọ ariwo, ti oun si ri pe nnkan ti sẹlẹ si ‘Elevator’ naa.

“Yara kẹsan an ni obinrin yii wa nigba to ransẹ pe ‘Elevator’ yii ko wa gbe oun lọ isalẹ. Mo si wa ni yara kẹjọ ti mo n ba ọrẹ mi sọrọ lọwọ, mo gbọ nigba to wọle, bni o se wọle ni ‘Elevator’ naa ja silẹ.”

O ni oun suure lọ si isalẹ lati yara kẹjọ ti oun wa, ti oun si igbiyanju lati si ilẹkun ‘Elevator’ naa sugbọn o nira

“A gbiyanji lati pe awọn osisẹ to n mojuto ‘Elevator’ sugbọn a ko ri wọn pe, a ransẹ pe awọn osisẹ panapana , wọn ni awọn wa ni Lekki, pe awọn n bọ. A wa nibẹ fun odidi wakati kan.”

Dokita Olumide ni nigba ti awọn pada ri ilẹkun naa si , Dokita Diaso bẹrẹ si ni kle pe oun ko fẹ ku bayii.

“Ti ko ba waye lonii, yoo waye lọla.”

Ijọba ipinlẹ Eko ba awọn mọlẹbi Dokita kẹdun.

Aworan ile wosan General Odan

Ijọba ipinlẹ Eko ti ransẹ ibanikẹdun si idile dotika Vwaere Diaso lori iku eeyan to jade laye nibi ijamba ‘Elevator’ to wa ni ile wosan General Odan.

Ninu atẹjade ti akọwe agba fun ẹka ijọba to n risi iroyin, Olumide Sogunle buwọlu fun awọn akọroyin salaye pe iroyin lo ba awọn ni ojiji lọjọ Isẹgun.

Gẹgẹ bi atẹjade naa se wi, igbimọ oniwadi lati ẹka eto ilera nipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadii lori ijamba naa.

Lafikun ni atẹjade naa fi da awọn dokita loju gbogbo ẹni to ba lọwọ ninu ijamba naa ni yoo ri ijiya ofin

Tani Dokita Vwaere Diaso?

Dokita Vwaere Diaso jẹ dokita onisegun oyinbo nto n gba ẹkọ ni ile wosan General ni Odan nipinlẹ Eko ki ọlọjọ to de lọjọ kinni oṣu kẹjọ, ọdun 2023.

Dokoita Diaso lo pari ni ile ẹkọ ninu oṣu keji ọdun 2022.

Gẹgẹ bi ọrẹ rẹ, Edidiong Ikpe se sọ, Diaso lo jẹ agbabọọlu apẹẹrẹ, ti wọn si kopa lasiko ti wọn wa ni fasiti Babcock

Ikpe lori ayẹlujara sapejuwe ọrẹ rẹ gẹgẹ ọmọ ti gbogbo obi fẹ ni

Dokita Diaso lo wa lori ayelujara lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu keje nigba to sọrọ lori iku oṣere Amẹrika Angus Cloud to ku lọjọ naa.