Irọ́ ńlá! kò sí “Hacker” kankan ò kọlu ẹ̀rọ ayélujára wa o, nọ́mbà yín wà ní ṣẹpẹ́ – Àjọ NIMC

Ajọ to n moju to kaadi idanimọ lorilẹ ede yi taa mọ si NIMC ti ṣalaye pe ko si akọlu kankan si awọn ẹrọ ayelujara ti wọn n fi akọsilẹ awọn ọmọ Naijiria si.Ọga agba ajọ naa, Onimọẹrọ Aliyu Aziz lo fi ọrọ yi lede lataari iroyin kan to jẹyo pe ajideta ori ayelujara kan ti ṣakolu si ẹrọ ayelujara wọn.Aziz ṣalaye pe ọpọlọpọ igbesẹ ni awọn ti gbe lati rii pe apamọ wọn lori ẹrọ ayelujara ni ko ri akọlu kankan.

O fi kun ọrọ rẹ pe irufẹ abo to daju jakejado agbaye ni wọn fi n da bo apamọ naa gẹgẹ bii ajọ to n daabobo akọsilẹ to ṣe pataki ju lọ nilẹ Naijiria.Aziz fi da awọn ọmọ Naijiria loju pe ajọ naa yoo tubọ maa sa gbogbo ipa rẹ lati rii pe abo to munadoko wa lori akọsilẹ to wa ni ikawọ wọn.O gboriyin fun awọn ile-iṣẹ ijọba bii Ọlọpaa, ẹṣọ oju popo ati ajọ to n ri si idanwo aṣewọ ile ẹkọ giga, JAMB fun bi wọn ṣe ni igbẹkẹle ninu ilana ti awọn fi kalẹ lori lilo nọmba idanimọ orilẹ ede yii.Aziz tun parọwa fun gbogbo ọmọ Naijiria ati olugbe lati rii pe wọn forukọ silẹ fun nọmba idanimọ eyi to jẹ ojulowo ọna lati ṣafihan eeyan to jẹ olugbe ilẹ yii ni ilana ti ofin.