Gbogbo àṣà àtijọ́ fún yíyàn Ọba, ṣíṣe ìsìnkú Ọba gbúdọ̀ dópin lónìí pẹ̀lú àṣẹ – Dapo Abiodun

Aworan Gomina Dapo Abiodun atawọn nkan ibilẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti tọwọ bọ iwe abadofin kan to faaye gba ilana tuntun lori igbesẹ lati yan Ọba ati ijoye ati igbesẹ isinku wọn bi wọn ba jẹ Ọlọrun nipe.

Iwe abadofin naa ni Gomina tọwọ bọ loju awọn to dabaa ofin tuntun naa – Awujale to jẹ Ori Ade ilẹ Ijebu, Oba Sikiru Adetona; Olu ti ilu Ilaro, Oba Kehinde Olugbenle; Akarigbo ti ilẹ Remo, Oba Babatunde Ajayi.

Ẹwẹ, ọkan lara awọn Ọba nla ipinlẹ Ogun ti ko si nibẹ ni Alake ti Egba, Oba Adetoun Gbadebo.

Gomina Dapo Abiodun ni o pọndandan lati boju wo ofin to ti wa nilẹ lati ọjọ yii tori pe ipinlẹ Ogun ko le tẹsiwaju lati maa faaye gba ofin to ti gbo lati aye atijọ to si n ṣe lodi si ẹtọ awọn Ọba yii ati ohun ti ipinlẹ naa duro fun.

Iwe abadofin naa lo ni akọle to sọ pe “Abadofin lati faaye gba bibọwọlu ilana yiyan Ọba, ifinijoye ati bi eeyan ṣe n juwe ipo Ọba ati ijoye ni ipinlẹ Ogun. Eyi ni ofin tuntun ọhun gbero lati mu ayipada ba ko lee ba igba mu.

Lara ohun to ba ofin naa jade ni pe yoo jẹ ẹtọ awọn l’Ọba l’Ọba lati yan iru ilana ti wọn ba fẹ ki wọn fi sin wọn yala ni ilana ẹsin wọn ni tabi tori awọn nkan mii.

Ẹwẹ, iyalẹnu fun ọpọ ni pe awọn Ọba alade kan gan jọ wa pẹlu gomina ni nigba to n buwọlu iwe abadofin yii ti gbogbo wọn si fọwọ sii.

Amọṣa awọn oniṣẹṣe ati ẹlẹsin ibilẹ tako ofin yii ti wọn si kede pe ọna ati ti aṣa ilẹ Yoruba wọ inu oko igbagbe lọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ṣugbọn awọn Kristẹni ati Musulumi ni awọn faramọ ti wọn si ṣapejuwe igbesẹ naa gẹgẹ bi eyi to dara.

Abiodun ni “ara awọn nkan to da yatọ ninu ofin yii ni wipe yatọ fun pe o wa lati mu agbega ba ilana yiyan Ọba ati Oloye, alaye kikun naa ti ofin yii ṣe paapaa fun igba ti Ọba kan ba waja dara”.

Alaye wọn ni wipe ofin yii yoo mu agbega ba eyi to ti wa nilẹ tẹlẹ ninu eyi ti ọpọlọpọ igbagbọ wa nipa bi wọn ṣe maa n sin awọn Kabiyesi.

Nibayii, ofin tuntun ni pe awọn mọlẹbi Ọba ati Ijoye lee lẹnu lọrọ lori bi wọn ṣe lee sin oku wọn. O ti faaye gba ki awn idile sọ bi wọn ṣe fẹ ṣe eto isinku lai ṣe ilana ibilẹ tabi iṣṣe kankan.

O kan sara si Awujale fun akitiyan ati ifarajin rẹ lati ri i daju pe ayẹwo ati atunṣe ofin naa yọri si rere ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin Naijiria to si tun gba waju awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin kọja toripe ohun tawọn eeyan fẹ mọ abajade rẹ ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Lara awọn tọrọ kan atawọn eekan to wa nibẹ ni agbẹjọro agba to tun jẹ kọmisna fun eto idajọ, Ọgbẹni Oluwsina Ogungbade, adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Kunle Oluomo, igbakeji adari ile igbimọ aṣofin

ipinlẹ Ogun, Akeem Balogun, akọwe ijọba ipinl Ogun, Ọgbẹni Tokunbo Talabi, Olori awọn oṣiṣẹ ijọba Ogun, Alhaji Afolabi Salisu, olugbaninimọran fun gomina, Ọgbẹni Dapo Okubadejo atawọn ọmọ igbimọ

mii. Gbogbo awọn wọnyii lo si fọwọ si ayipada ofin to ti aṣa iṣẹṣe lẹyin yii.