Tinubu hùwà ọdàlẹ̀, Ọlọ́run kó sì ní gbà fún un lórí èròngbà rẹ̀ – Ohanaeze Ndigbo

Alex Ogbonnaya ati Bola Tinubu

Lati igba to ti kede erongba rẹ lati du ipo aarẹ lawọn iriwisi ọtọọtọ ti n jẹyọ si Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.

Tinubu to jẹ eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC kan si aarẹ Muhammadu Buhari lọjọ Aje l’Abuja to si sọ fun awọn oniroyin pe oun ti fi to aarẹ leti pe oun fẹ dupo lọdun 2023.

Ninu awọn to ti n fesi si ikede yi la ti ri Ẹgbẹ idagbasoke ọmọ ẹya Igbo ni Naijiria Ohanaeze Ndigbo ti wọn si ni Tinubu gbẹyin bẹbọ jẹ ni pẹlu ikede naa.

Agbẹnusọ Ohanaeze Ndigbo Alex Ogbonnia sọ pe awọn mọ Tinubu si ẹni to lẹri ọkan.

Tori naa ohun to tọ ni pe ki Tinubu patakii iṣedeede ati dọgbadọgba.

O ni ikede yi dabi ki eeyan mọọmọ maa fi iya jẹ awọn eeyan agbegbe ilẹ Igbo nitori asiko ti wọn lo to yii lati jẹ ipo aarẹ.

Ọgbẹni Ogbonnia sọ fun BBC pe ikede naa fihan pe Tinubu fẹ da omi alafiaa Naijiria ru ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Gbogbo eeyan ni ikede yii ya lẹnupẹlu bi gbogbo nkan ti ṣe dori kodo yii. Awa ẹya Igbo lo kan lati jẹ aarẹ o si yẹ ki Tinubu sọra ko si yago fun nkan ti ko bojumu”.

O tẹsiwaju pe ”Ọlọrun ko ni gba fun pẹlu erongba rẹ yi nitori ko si lẹyin rẹ”

Bola Ahmed Tinubu ko tii fesi si ọrọ yii.

Nigba to n kede pe oun ti sọ fuin aarẹ, o ṣalaye pe oun ṣi n jiroro pẹlu awọn eeyan lori erongba rẹ.

Pẹlu bi idibo aarẹ ṣe n kan lẹkun gbọngbọn yi, ọpọ awọn ẹya lo ti n lọgun pe o yẹ ki wọn jẹ ki ipo yi kari ni.

Labẹ ofin Naijiria, ko si aaye fun ṣiṣe aarẹ ni ṣiṣẹntẹle laarin awọn ẹya Naijiria ṣugbọn ọpọ igba lawọn oloṣelu maa n sọ pe awọn maa n fẹnu ko lori ẹya tawọn yoo dibo yan sipo aarẹ.

Lati igba ti Naijiria ti nṣe oṣelu alagbada, ko ti si eeyan ẹya Igbo kankan to di ipo aarẹ mu.

Wọn ti ṣe igbakeji aarẹ labẹ ologun ati oloṣelu ṣugbọn ko si aarẹ Igbo ninu akọsilẹ itan Naijiria.

Ní tiwa, inú wa dùn pé Tinubu fẹ́ du ipò Ààrẹ, a fọwọ́ síi pẹ̀lú – Yoruba Council of Elders

Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igbimọ agba ilẹ Yoruba, Yoruba Council of Elders, ti sọ pe inu awọn dun bi asiwaju Bola Tinubu ṣe fi erongba rẹ lede lati dije du ipo Aarẹ Naijiria.

Akọwe agba ẹgbẹ naa, Kunle Olajide lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

O ni “Ipinnu yẹn daa pupọ, o si dun mọ wa ninu.”

“Inu wa dun si pe ọmọ wa to kajuẹ to si koju oṣuwọn lo jade lati du ipo Aarẹ.”

Olajide sọ pe o yẹ ki awọn ọmọ ile Yoruba gbaruku ti Tinubu lati di Aarẹ Naijiria.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ki si nnkan bababa ninu ọrọ ti awọn n sọ kiri pe Tinubu duro ti ẹya Hausa.

Akọwe WCE naa tẹsiwaju pe akoko ti to naa bayii ti awọn ẹya Hausa yoo ti Tinubu lẹyin.

O fin kun pe ẹyin rẹ ni awọn yoo wa titi ti ọmọ Yoruba miran to tun koju oṣuwọn yoo fi erongba rẹ lede lati dije du ipo Aarẹ lọdun to bọ.

Lẹyin naa lo rọ Tinubu lati lọ ba awọn alẹnulọrọ ilẹ Yoruba sọrọ ki wọn le ṣatilẹyin fun.

Afọbajẹ tí mò ń ṣe látọdún yìí ti tó, ẹ jẹ́ kí èmi náà dádé Ààrẹ – Tinubu

Tinubu

Oríṣun àwòrán, @queen_beee_beee

Eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ti fun awọn to n sọ pe ipo Aare ko tọ si lesi.

O ni ko si ofin to de oun lati du ipo naa.

Tinubu lo sọ ọrọ naa lasiko ifọwerọ kan lori ẹrọ amohunmaworan TVC.

O ni o ti pẹ ti oun ti n ṣamọna awọn eeyan miran lati de ipo adari, akoko ti to fun oun naa lati dade Aarẹ.

Tinubu ko ipa ribiribi ninu idasilẹ ẹgbẹ oṣelu APC, o is ṣe atilẹyin ti ko ṣe fẹnusọ lati gbe Muhammadu Buhari de ipo Aarẹ lọdun 2015.

Ọjọ Aje ni Tinubu kede pe oun ti fi to Aarẹ Buhari leti pe oun yoo dije du ipo Aarẹ lọdun 2023.

Nigba to n dahun awọn ibere awọn akọroyin, o ni oun ko ni dije labẹ akọle “Afọbajẹ.”

O ni “Ni ti afọbajẹ, mi o tii ri fila afọbajẹ ri.”

“Ṣugbọn ootọ to wa nibẹ ni pe ko si ofin to sọ pe afọbajẹ funra rẹ ko le jẹ ọba, ayafi to ba gbẹmi eeyan lọna aitọ nikan.”

Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹri naa sọ siwaju si pe Aarẹ Buhari ko lodi si erongba oun lati di Aarẹ Naijiria.

O ni “Oloṣelu ni Buhari, ko si ni ki n ma diju du ipo Aarẹ.”

O pari ọrọ rẹ pe oun ni iriri ati imọ to to lati dari Naijiria gẹgẹ bii Aarẹ.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Àwàdà kẹríkẹrì ni ìgbésẹ̀ Tinubu láti du ipò Ààrẹ – Bode George

Tinubu and Bode George

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Jibrin Deba/Adeleke Abel Ayoade

Eekan ẹgbẹ oṣelu PDP, Oloye Bode George ti juwe ipinnu asiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu lati dije du ipo Aarẹ Naijiria gẹgẹ bii awada kẹrikẹri.

Bode George lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹlẹ Punch, lẹyin ti Tinubu kede pe oun ti sọ fun Aarẹ Buhari pe oun yoo dije lọdun to n bọ.

O ni “Awada lasan ni ipinnu Tinubu lati dije du ipo Aarẹ nitori ipo Aare Naijiria kii ṣe fun awọn alawada bii Bola Tinubu.”

Bode George

Oríṣun àwòrán, Lagos4Lagos

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

“Ẹ wo bo ṣe ṣi awọn alumọni ipinlẹ Eko lo, o jẹ ohun iyalẹnu pe yoo tilẹ le lala ati de ipo Aarẹ Naijiria. Ko mọ ohun to n sọ rara.”

Igbakeji alaga gbogbogbo ẹgbẹ PDP tẹlẹ naa sọ siwaju si pe iyalẹnu nla ni yoo jẹ fun Tinubu ibi ti ọrọ naa yoo ja si fun, ati bi awọn to n fọkan tan yoo ṣe ja kulẹ.

Bode George sọ pe Guusu iwọ-oorun Naijiria ní awọn adari to dantọ lati dari Naijiria, Tinubu kii ṣe ọkan lara wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni yoo jẹ ohun abuku fun awọn eeyan Guusu-iwọ oorun Naijiria to ba jẹ pe Tinubu nikan ni wọn le ri fa ọwọ rẹ soke lati dije du ipo Aarẹ.

O pari ọrọ rẹ pe o ṣeni laanu pe inu ilegbe Aarẹ l’Abuja gan ni Tinubu ti kede ipinnu rẹ ọhun.

Tinubu, to jẹ gomina ipinlẹ Eko laarin ọdun 1999 si 2007 kede pe lọjọ Aje pe oun ti fi to Aarẹ Buhari leti pe oun yoo dije du ipo Aarẹ ninu idibo ti yoo waye lọdun 2023.

O ni o ti ṣe diẹ ti oun ti n ṣatilẹyin fun awọn eeyan lati de ipo adari, amọ bayii akoko ti to fun oun lati tọ ipo Aarẹ wo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Mo tí fí èròngbà mí láti du ìpò ààrẹ tó Buhari létí-Bola Tinubu

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina

Lẹyìn ìpàdé Aso Rock Tinubu tú kẹ́kẹ́ ọ̀rọ̀ lórí èròngbà rẹ̀ láti du ipò ààrẹ Nàìjíríà ní 2023

Agbaọjẹ oloselu ẹgbẹ APC nii Bola Ahmed Tinubu ti sọ pe oun ti fi erongba rẹ to aarẹ Buhari leti nipa dudu ipo aarẹ lọdun 2023.

Tinubu tu kẹkẹ ọrọ yi lẹyin ipade to ṣe pẹlu aarẹ Buhari ni ile ijọba to wa ni Aso Rock ni Abuja.

Tinubu sọ pe erongba lati jẹ aarẹ Naijiria jẹ eleyi toun ti ni tipẹ ati pe oun ni ikapa lati ṣe atunsẹ iru eleyi toun ṣe gẹgẹ bi Gomina lEko fun orileede Naijiria.

Nigba tawọn akọroyin beere lọwọ rẹ nipa ọrọ to n lọ pe igbakeji aarẹ Yemi Osiunbajo naa fẹ dupo aarẹ, Tinubu sọ pe oun ko ni mẹnu ba ọrọ naa.

Ọpọ lo ti n sọrọ lori erongba Tinubu lati du ipo aarẹ bo ti lẹ jẹ wi pe ko ti kede sita gbangba faraalu pe oun fẹ jẹ aarẹ.