Inú ìbẹ̀rùbojo ni a wà báyìí ni Ukraine léyìn tí Russia kógun wọlé – Sunday Adelaja

Sunday Adelaja

Oríṣun àwòrán, @THEWILLNG

Ọmọ Naijiria to n ṣiṣẹ alufaa lorilẹ-ede Ukraine, Sunday Adelaja, ti ke gbajare lẹyin ti Aarẹ orilẹ-ede Russia ko ogun lọ ba awọn eeyan Ukaraine.

Adelaja sọ pe oun jẹ ọkan gboogi lara awọn eeyan ti Aarẹ Vladimir Putin n wa ẹmi rẹ lati pa.

Pasitọ naa to fi ilu Kyiv ṣe ibugbe sọ pe oun wa lara awọn eeyan ti Putin fẹ pa ti awọn ọmọ ogun rẹ ba ti gba ilu naa tan.

Fun idi eyii, Adelaja ni oun atawọn ẹbi oun ti sa asala fun ẹmi wọn lọ si agbegbe kan ti ko darukọ.

O ni “Gẹgẹ bi ohun ti a mọ nipa ifimufinlẹ ilẹ Amẹrika, Putin ti kọ orukọ awọn eeyan ti wọn fẹ pa silẹ, awọn eeyan naa kii ṣe eeyan lasan, amọ wọn jẹ awọn alẹnulọrọ laarin ilu.”

“Mo jẹ ọkan lara awọn eeyan ọhun.”

“Mo ti mọ eyii lati ọdun 2015 nitori lati ọdun naa lọhun ni Putin ti fi mi si ara awọn eeyan ti kọ fẹ ri soju.”

“Putin ti mu mi gẹgẹ bii ọta rẹ lati nnkan bii ogun ọdun sẹyin, koda, o ti fofin de mi pe mi o gbọdọ wọ orilẹ-ede Russia.”

Lati Ọjọbọ ni awọn ọmọ ogun Russia ti bẹrẹ si n kọlu orilẹ-ede Ukraine nitori ipinnu Ukraine lati darapọ mọ ajọ NATO.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ta ni Sunday Adelaja?

Sunday Adelaja jẹ oluṣọagutan to n fi ilu Kyiv, ni Ukraine ṣe ibugbe, nibẹ naa lo ti n ṣe iṣẹ iyinrere.

Adelaja jẹ ọmọ bibi ilu Ijebu Ode, ni ipinlẹ Ogun.

Wọn bi ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Karun un, ọdun 1967, orukọ iyawo rẹ si ni Abosede Adelaja.

Ọ dun 1993 lo da ijọ “Embassy of the Blessed Kingdom of God for All Nations” silẹ ninu ile rẹ ki ijọ naa to yi orukọ pada si “World of Faith Bible Church” lọdun 1994.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ẹka ijọ Adelaja le ni ẹgbẹrun kan kaakiri agbaye yatọ si awọn to wa ni Ukraine.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ