Ajínigbé ṣe ìkọlù ní Kaduna akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta fara gbọta, 57 míìràn dàwátí

Aworan ọlọde to gbe ibọn lọwọ lati koju awọn janduku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn afurasi agbesunmọmikan ti ṣeku pa eeyan meje ninu ikọlu ọtọọt to waye ni Kuriga loju ọna marose Birnin Gwari -Kaduna ni ipinlẹ Kaduna.

Ninu awọn to farakasa iṣẹlẹ yi la gbọ pe akẹkọọ ile ẹkọ Government Science Secondary School, Birnin-Gwari wa ẹni ti ibọn ba lasiko to n lọ forukọsilẹ fun idanwo JAMB.

Ọrọ yi jẹyọ ninu atjade kan ti ẹgbẹ idagbasoke Birnin Gwari Vanguard for Security and Governance fi sita ti alaga wọn Ibrahim Nagwari si buwọlu lọj Abamẹta.

Atẹjade naa fi kun eeyan mẹta miran naa farapa nigba ti awọn ajinigbe yi si gbe eeyan mẹtadinlọgọta gbe salọ.

Ẹgbẹ idagbasoke yi sọ pe ọrọ aabo nipinl Kaduna ti mẹhẹ kọja afẹnusọ laarin wakati mẹrinlelogun.

”Loni ọjọ Abamẹta,ninkan bi ago mẹwaa aarọ,akẹkọọ ile iwe girama Science Secondary School Birnin Gwari kan moribọ pẹlu apa ọta ibọn lejika rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

”Akẹkọọ yi n lọ si Kaduna lati forukọsilẹ fun idanwo JAMB ni o kagbako awọn alaburu yi”

Ẹgbẹ naa tẹsiwaju pe niṣe lawọn agbesunmọmi yi ṣina ibọn bo ọkọ ti o wa ninu rẹ ni abule Manini.

Yatọ si akẹkọọ yi, atẹjade ẹgbẹ yi sọ pe awọn agbebọn tun ṣe ikọlu si abule Unguwar Bula Unguwar Dafillo ati Ijinga ni agbegbe Randagi lọjọ Jimọ.

Gẹgẹ bi wọn se wi, nkan bi ago mọkanla ni ikọlu yi waye ti wọn si ṣoro fun nkan bi wakati mẹrin.

Eeyan meje ni wọn lo ku ninu awọn ikọlu yi ti awọn eeyan ko si ribi kopa ninu irun Jimọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ki ni Ijọba atiagbofinro sọ si ọrọ yi

BBC Yoruba gbiyanju lati ba alukoro ọlọpaa Kaduna Mohammed Jalige sọrọ lori foonu.

Jalige gbe ipe rẹ ṣugbọn ni kete to gbọ taa beree nipa ikọlu yi, o sọ pe ki a fun oun ni asiko wipe ”maa pe yin pada”

Ni ti ijọba Kaduna ko si iroyin nipa iṣẹlẹ yi loju opo Kọmisana fun eto aabo labẹlẹ Samuel Aruwan tabi loju opo Gomina Nasir El Rufai.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ni nkan bi ọjọ mẹta sẹyin ni Gomina Nasir El Rufai sọ fawọn akọroyin nilu Abuja pe awọn ọlọpaa ati ologun kan n lẹdi apopọ pẹlu awọn janduku nipinlẹ naa.

O ni iwadii awọn tọka si ibaṣepọ laarin wọn ṣugbọn o ni awon ko ti ribi fidi rẹ mulẹ tanyanyan.

Ipenija aabo ni Kaduna n kọ araalu lominu

Ni ipinlẹ Kaduna, ipenija aabo jẹ eleyi to ti wa tipẹ.

Bi wọn ko ba maa koju ija ẹlẹyamẹya tabi ija laarin awọn musulumi ati Kristeni, ijinigbe ati ikọlu janduku jẹ ohun to tun jẹ ipenija fun ipinlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bi a ko ba gbagbe, iroyin gbode laipẹ yi pe awọn ajinigbe janduku ti wọn le kuro loju ọna Kaduna si Abuja tun ti bẹrẹ iṣẹ pada ti wọn si ṣeku pa ọpọ eeyan.

Eleyi nikan kọ, awọn janduku a maa yabo ile ẹkọ ti wọn a si tun maa ji awọn akẹkọọ gbe lai fi ti ọjọ ori wọn ṣe.