Ọmọ ọdún mẹ́tàlá gún ènìyàn pa nítorí owó ìrèké ní ìpínlẹ̀ Borno

Ireke

Oríṣun àwòrán, Others

Ọmọ ọdún mẹ́tàlá gún ènìyàn pa nítorí kò san owó ìrèké ní Borno

Àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno ní àwọn ti nawọ́ gán ọmọ ọdún mẹ́tàlá kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abdullahi Sanusi fún ẹ̀sùn pípa ènìyàn látàrí tí ẹni náà láti san owó ìrèké.

Abdullahi lo n ta ireke sugbon wọ̀n ni o maa n binu pupọ.

Kini ajọ ọlọ́pàá sọ si isẹ̀lẹ̀ yii ni Borno?

Kọmíṣọ́nnà àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno Abdul Umar nínú àtẹ̀jáde kan ní olóògbé náà, Mohammed Abdullahi kú sí ilé ìwòsàn ìkọ́ni Maiduguri (UMTH).

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Umar ṣàlàyé pé olóògbé ọ̀hún ẹni ọdún mọ́kàndínlógún fi tipátipá mú ìrèké Abdullahi Sanusi láì fún un ní owó, nígbà tí ìyẹn sì tún bèèrè owó rẹ̀ ní ṣe ló dá bàǹtẹ́ ìyà fún un.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ó ní èyí ló fà á tí Abdullahi Sanusi fi mú ọ̀bẹ tó ń fi ń gé ìrèké tó fi gún Mohammed Abdullahi lọ́rùn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Umar tẹ̀síwájú pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé ní Mallawan, Gidan Dambe mú ki Mohammed Abdullahi ṣèṣe púpọ̀ tí wọ́n sì sáré gbe lọ sí ilé ìwòsàn UMTH níbi tó kú sí.