Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ ò! Ajá mẹwàá yà ọmọ ọdún méjì jẹ ní Anambra

Bullmastiff

Oríṣun àwòrán, Bullmastif/Facebook

Ọjọ ayọ ni ọjọ ti awọn obi ba mu ọmọ wọn sile ẹkọ lati forukọsilẹ fun ọmọ wọn.

Amọ ọjọ ayọ yi di ibanujẹ fawọn obi kan ti aja mẹwaa yabo ọmọ ọdun meji wọn ti wọn si ya yanayana.

Ni ile ẹkọ aladani kan to wa ni Amokpo Umuanunwa ni ipinlẹ Anambra ni iṣẹlẹ buruku yi ti waye.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iwe iroyin Naijiria kan The Nation ṣe jabọ, awọn obi ọmọ taa n wi yi mu ọmọ lọ lati w ile iwe ni ki o to kan agbako iku gbona.

A gbọ pe oludasilẹ ile ẹkọ naa Chinedu Oka n ṣin aja ninu ọgba ileewe naa toun ti ikilọ tawọn ilu ti kilọ pe ko ma sin aja nibẹ.

Araadugbo kan ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni nigba tawọn obi ọmọ yi n buwọlu iwe iforukọsilẹ ni ọmọ naa tasẹ agẹrẹ l sibi tawọn aja wa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni ”Aja mẹwaa lo wa nibẹ ti wọn si bẹrẹ si ni bu ọmọ naa jẹ.Ko si eeyan kankan ni tosi lati doola rẹ”

Ki a to wo ka to fọ, awọn araalu ti fi ibinu wọ inu ọgba ileẹkọ naa ti wọn si yinbọn pa gbogbo aja to wa nibẹ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yi mulẹ, olori abule ilu Nteje, Igwe Rowland Odegbo sọ pe eewọ ni aja sisin ni ilu awọn ati pe awọn yoo fi ijiya to tọ jẹ arakunrin to ni ileewe naa.

O ni ”arakunrin naa mọ pe a klo faye gba aja sinsin ṣugbọn o keti ikun to si ko aja sinu ọgba rẹ.”

”Lọdọ wa, bi igba pe o ṣeku pa eeyan ni nkan to ṣe yi awọn to si yẹ yoo fi ijiya to t jẹ nitori a ko faaye gba iwa aburu”

O fi kun pe awọn lọwọ si bi awọn ọdọ ile ti ṣe dana sun awọn aja naa lẹyin ti wn pa wọn.

Ikenga Tochukwu to jẹ alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Anambra ti fidi ọrọ yi mulẹ to si ni alaafia ti pada si ilu.