“Buhari, to bá fún Fani-Kayode ní ipò, àwa ọ̀dọ́ yóò fí ẹ̀họ́nú hàn”

Femi Fani-Kayode

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Fani-Kayode

Eekan kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Ben Adaji ti ṣeleri pe, ohun yoo ṣe agbatẹru fun awọn ọdọ kaakiri orilẹede Naijiria lati ṣe iwọde, ti aarẹ Buhari ba fun Femi Fani Kayode ni ipo ni ijọba rẹ.

Ben Adaji sọ eyi lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ilu Jalingo ni ipinlẹ Taraba.

O wa kilọ fun awọn alaṣẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC lati ṣọra gidigidi fun Fani-Kayode to jẹ minisita tẹlẹri fun ọrọ oju ofurufu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ọdalẹ eniyan lati igba de igba ni Fani-Kayode, ki wọn si ṣọra fun un.

Adaji ni o ṣoro lati fi ọkan tan Fani-Kayode to kuro ni ẹgbẹ oṣelu APC ni ọdun 2014 lọ si ẹgbẹ oṣelu PDP, lẹyin to ṣe apejuwe aarẹ Buhari pe o n sa gbogbo ipa rẹ lati sọ Naijiria di orilẹede awọn Musulumi nikan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

O ni Fani-Kayode sọ nigba naa pe aarẹ Buhari ni ero lati fi iya jẹ awọn ọmọ Naijiria lasiko iṣejọba rẹ.

Bakan naa lo fikun pe Fani Kayode lati ọdun 2014 lo ti n sọrọ aarẹ Buhari ni aida pẹlu awọn ọrọ kubakugbe to ma n sọ si aarẹ lori ẹrọ ayelujara.

Eekan ni ẹgbẹ oṣelu APC, Ben Adaji wa rọ aarẹ Buhari ko tun ero rẹ pa nigba Fani-Kayode.

Adaji ni kio aarẹ Buhari kọkọ wo awọn ti wọn duro ti wọn si satilẹyin fun ẹgbẹ naa lati fun wọn ni ipo, ki wọn to lọ si ọdọ iru eniyan bi Fani-Kayode.

Ọpọlọpọ eniyan lo ti bu ẹnu atẹ lu bi Fani-Kayode ṣe pada si ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin ọrọ kubakugbe to si sọ nipa ẹgbẹ oṣelu naa ati aarẹ Muhammadu Buhari.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ