Bí egungun bá há ọ lọ́fun, wo ohun méje tó ṣe láti yọ́

Ẹja dindin pẹlu egungun

Oríṣun àwòrán, other

Nnkan ti a fẹ ṣe idanilẹkọ fun ara wa le lori yii, ko fẹẹ si ẹni ti ko ti ṣẹlẹ si ri. Bi ko ba ti ṣẹlẹ, o ṣeeṣe ki o waye nitori o nii ṣe pẹlu ounjẹ jijẹ, ko si si ẹni ti yoo sọ pe oun kii jẹun.

Lọpọ igba ti eeyan ba n jẹun ni egungun maa n ha si ọfun; ti iru nkan bayii ba wa ṣẹlẹ, inira nla lo maa n ko ba ẹni to ba sẹlẹ si, to si maa n gba oorun loju eeyan.

Koda, o le di egbo nla, ti eeyan yoo si nawo si yatọ si pe o see se ki onitọun ma le mu isẹ oojọ kankan se lasiko ti inira naa ba fi waye.

Amọ ko to di pe eeyan morile ile iwosan lati wa ọna abayọ si isẹlẹ inira yii, eeyan naa le tiraka ninu ile rẹ lati bọ lọwọ inira ti egungun naa n mu wa, to si le yọ funra rẹ lai si ewu.

Ohun meje ti a si le se ree, bi egungun ba ha si eeyan ni ọna ọfun ree:

Jijẹ ọgẹdẹ:

Ọgẹdẹ

Oríṣun àwòrán, other

Ọgẹdẹ jẹ eso kan to rọ daadaa to si le ran wa lọwọ lati ti egungun to ba ha si ọfun wa lọ silẹ. Bi egungun naa ba kọ ti ko fẹ kuro, ṣaa ti wa ọgẹdẹ bo jẹ.

Nitori pe ọgẹdẹ rọ, yoo jẹ ki egungun naa lẹ mọ ọgẹdẹ naa, ti yoo si kuro ni ọna ọfun.

Burẹdi ati omi:

Buredi ati omi

Oríṣun àwòrán, other

Ọna miran ree lati fí yọ eegun kuro l’ọna ọfun, ko si nira lati ṣe.

Ri burẹdi sinu omi, ki o si jẹ ninu rẹ. Gbe burẹdi tutu yii mi lẹẹkan naa, ki o ba le ti egungun naa kuro nibi to ti n se idiwọ.

Ọgbọn yii a tun maa jẹ ki egungun naa ba burẹdi lọ sinu ikun lati ọna ọfun lai mu inira wa.

Wu ikọ pẹlu agbara:

Obinrin kan n wukọ

Oríṣun àwòrán, other

Eyi naa jẹ ọna kan gboogi ti o le fi yọ eegun lọna ọfun rẹ. Bi eegun naa ba ṣe tobi si, ni yoo tọka bi a o ti ṣe wukọ si.

Ti eegun ọhun ko ba tobi ju, o le wukọ diẹ, ti yoo si jade si enu rẹ. Iwọ ṣaa ti wukọ nigbakuugba ti o ba gburo pe nkankan ba ha si ona ọfun rẹ.

Lilo ororo Olive Oil:

ororo

Oríṣun àwòrán, other

Ororo yií maa n ṣiṣẹ daada lati yọ egungun to ba ha si ọfun, lilo rẹ kò sì le rara.

Iwọ ṣaa ti bu ororo yii diẹ sinu ikeemu, ko si di si ọna ọfun.

Mimu omi ko le ṣiṣẹ daada bi ororo yii nitori pe omi fẹlẹ ju ororo lọ.

Yiyọ ti ororo Olive maa n yọ, yoo tun jẹ ki egungun yii kuro lọna ọfun rẹ nirọrun ati ni kiakia.

Ohun mimu ẹlẹrindodo:

Ohun mimu ẹlẹrindodo to wa ninu ife

Fun aimọye ọdun ni awọn dokita ti maa n lo ohun mimu ẹlẹrindodo lati yọ egungun to ba ha si ọna ọfun kuro.

Idi ni pe ni kete ti o ba mu awọn ohun mimu ẹlẹrindodo yii tan, to de inu ikun rẹ, ni eroga afẹfẹ gaasi yoo wa nikun rẹ, to si maa mi awọn gaasi yii jade.

Afẹfẹ gaasi to n mi jade yii ni yoo seranwọ lati ti egungun naa jade nibi to ha si ni ọfun rẹ.

Mimu omi Vinegar:

omi Vinegar

Oríṣun àwòrán, The maids

Eroja omi Vinegar ni eroja kan ti wọn n pe ni asidi (Acid) ninu, ta ba si mu lasiko ti egungun ba ha wa lọfun, eyi yoo seranwọ lati fọ egungun naa si wẹwẹ, ti yoo si tun rọ lati tete gbe mi.

A le mu sibi omi Vinegar meji, ka da pọ̀ mọ̀ ife omi kan, ka si gbe mu.

Bakan naa, a tun le mu sibi Vinegar kan lẹsẹkẹsẹ ti egungun ba ha si wa ni ọna ọfun lai po Vinegar naa pọ mọ omi kankan.

Eroja omi Vinegar yii ko fi bẹẹ koro, paapaa ta ba po papọ mọ oyin.

Buredi ati Bọta:

Burẹdi ati Bọta

Oríṣun àwòrán, Klye Levesque

Ti egungun ba ha si wa lọna ọfun, a tun le mu burẹdi, ka fi bọta (Butter) yi daadaa, eyi ti yoo gba egungun naa mu lọna ọfun, ti yoo si wọ wa sinu ikun wa.

Ẹ jẹ burẹdi naa, kẹ si ri pe ẹ fi itọ po daadaa ni ẹnu, ko to di pe ẹ gbe mi lẹẹkan naa.

Amọ ẹ ri pe ẹ gbe omi si ẹgbẹ yii, ti ẹ mu le ounjẹ yii lori, eyi ti yoo tete san egungun naa ati burẹdi pẹlu bọta wa silẹ.

Bi a ba wa se awọn ohun mẹjọ yii, ti egungun naa ko yọ, yoo dara ka gba ile iwosan lọ lati lọ ri dokita onisegun oyinbo, ko to di pe ọrọ naa yiwọ.