Ìkókó bẹ̀rẹ̀ nǹkan oṣù lọ́mọ oṣù mẹ́rin, ó tún ní àìsàn jẹjẹrẹ ilé ọmọ

Beulah ati iya rẹ

Oríṣun àwòrán, Standard, Getty Images

Kayeefi darapọ mọ eemọ gogoro gbaa ni iroyin yii eyi ti a ko gbọ iru rẹ ri, to si soro gbagbọ.

Ọmọdebinrin kekere kan taa pe ni Beulah, lati bo aṣiri orukọ rẹ la gbọ pe o bẹrẹ si ni ṣe nkan oṣu, tawọn agba obinrin maa n ṣe, nigba to pe oṣu mẹrin pere.

Ọmọ naa to bẹrẹ si ni ṣe nkan oṣu ti ni ọpọ idojukọ bayii, to si ti bori aisan jẹjẹrẹ kan to n jẹ sex cord stromal tumors gẹgẹ bi awọn dokita ṣe ṣe apejuwe rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

“Awọn nkan to n fa aisan yii le maa tu homoonu to n mu kawọn ẹya ara fun ibalopọ tete jade siita. Wọn tun maa n pee ni sex cord-gonadal stromal tumor.

Iya ọmọ naa, taa pe ni Faube lati bo aṣiri orukọ rẹ, sọ fun iwe iroyin Standard, ni ile wọn to wa ni Kakamega County ni Kenya pe, ọmọ oun ni aisan jẹjẹrẹ ile ọmọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Beulah ni akọbi awọn ọmọ iya rẹ, ti wọn si bi i ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹrin ọdun 2019.

Iya rẹ ranti pe nigba to bii, iwọn 4.2kg lo wọ̀n, to si wa ni ilera pipe.

Amọ gbogbo nkan bẹrẹ si ni dẹru ba iya ọmọ naa nigba ti ọmọ rẹ pe oṣu mẹrin, to si bẹrẹ si ni fi ami ọmọbinrin to ti balaga han, ti nkan bii irorẹ́ si bẹrẹ si ni han loju rẹ, ti oloyinbo n pe ni acne tabi pimples.

Ọyan rẹ n tobi sii, irun si bẹrẹ si ni hu labẹ rẹ ati abiya rẹ.

Lẹyin oṣu kan ami naa yọju, Bibrian bẹrẹ si ni sun ẹjẹ loju ara rẹ.

“Isun ẹjẹ naa lo ọjọ marun,”, iya rẹ lo sọ bẹẹ, eyi to si jẹ pe iye ọjọ̀ to tọ ti awọn obinrin fi n ṣe nkan oṣu niyẹn.

Faube ba gbe ọmọ rẹ lọ si ile iwosan fun ayẹwo lati mọ ohun to n se e.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọkọ mi ti kọ mi silẹ tori abuku ilera ọmọ mi – Mama Beulah

Iya Beulah ni “Wọn tọju ọmọ mi fun aisan inu ẹjẹ, wọn si fun un ni oogun” amọ iya rẹ ni iṣe ọmọ naa ko yi pada.

Ni oṣu to tẹle e, o tun ṣun ẹjẹ labẹ,” gẹgẹ bii pe o n ṣe nkan oṣu”, iya Bibian sọ pe oun ranti bi ogun yii ṣe bẹrẹ toun si n baa fa a.

Nibayii, ọkọ Faube ti kọ ọ silẹ lẹni to fẹ ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹta ọdun 2018.

Faube ni oun n ti ile iwosan kan lọ si omii lati wa iwadii ijinlẹ si ohun to n ṣe ọmọ oun ṣugbọn ko fi bẹẹ sohun to ti ibẹ jade.

O ṣalaye bo ṣe ya owo lọwọ ọrẹ, ẹbi ati ṣọọṣi ko ba le san oke nla owo itọju ọmọ rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ