A tako Funke Akindele tí Jandor mú ní igbákejì rẹ̀ ló fi gba òdo nínú ìbò gómìnà – PDP Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti fesi si ẹsun ti oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP, Abdulazeez Olajide, ti wọn n pe ni Jandor fi kan ẹgbẹ lẹyin idibo sipo gomina to waye nipinlẹ Eko.

Jandor lo fidi rẹmi ninu idibo naa, ti gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti ẹgbẹ oṣelu APC si wọle fun saa keji.

Ọjọ Satide, ọjọ kejidinlogun osu kẹta ọdun 2023 ni eto idibo naa waye.

Lẹyin idibo naa ti Jandor ba BBC Yoruba sọrọ, lo ti ni awọn agba ẹgbẹ to n ṣiṣẹ tako oun lo jẹ ki oun fi idi rẹmi ninu idibo naa.

Jandor ko dibo ri, ko si fi ara balẹ, se lo n se bii ẹni to mọ gbogbo nnkan – PDP Eko

Amọ awọn asaaju ẹgbẹ oselu PDP ti kan si BBC Yoruba lori ẹsun ti Jandor fi kan wọn naa, ti wọn si salaye idi tawọn se tako aseyọri oludije gomina ti ẹgbẹ fa kalẹ naa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Abiola Ismail ni yiyan gbajugbaja oṣerebinrin, Funke Akindele ni ko ba awọn agbaagba ẹgbẹ lara mu, ti wọn si sọ fun Jandor to jawọ ninu igbesẹ naa.

Amọ o ni se ni Jandor fi aake kọri lati se bẹẹ, to si tẹsiwaju lati kede Funke Akindele bii igbakeji rẹ fun gbogbo araye.

Abiola ni ‘’Igbakeji oludije to mu, lo kọkọ fa wahala nitori o lodi si ẹgbẹ lori ẹni to yan gẹgẹ bi igbakeji rẹ.’’

‘’O tun kọ lati ba awọn ẹgbẹ ṣe lati ijọba ibilẹ, n se lo n ṣe bi ẹni pe o mọ gbogbo nkan, bẹẹ ko ṣe idibo ri amọ ko fi ara balẹ rara.’’

‘’Ninu ẹgbẹ PDP ta wa yii, ẹgbẹ to ni ẹtọ ni ti Jandor si gbọdọ bọwọ fun ni.’’

‘’Nitori naa oun fun ara rẹ lo ṣiṣẹ to fi gba ọdọ nitori awọn igbesẹ to gbe.’’

Aworan

Àìbọ̀wọ̀ fún àgbà ló mú kí Jandor gba òdo nínú ìbò gómínà l‘Eko- PDP

Abiola Ismail tun tẹsiwaju pe aibọwọ fun awọn agbaagba ẹgbẹ oselu PDP lo mu ki Jandor gba odo ninu idibo sipo gomina to waye ni ipinlẹ Eko.

‘’Jandor ko farabalẹ lati tẹlẹ ofin ẹgbẹ, n ṣe lo n tẹlẹ garagara’’

Abiola ni ki eniyan to le wa sinu ẹgbẹ PDP lati wa dije du ipo gomina , o yẹ ko ti lo ọdun kan si meji ninu ẹgbẹ.

Amọ ko ri bẹẹ fun Jandor, ti awọn agba ẹgbẹ si gba laaye ki o darapọ mọ wọn.

‘’Nigba to wa, n ṣe lo dọbalẹ pe ki wọn gba oun tọwọtẹṣẹ amọ to wa kẹyin si wọn bayii.

‘’Awọn ọrọ to sọ yii ko fidi imulẹ rara nitori Jandor ko farabalẹ lati mọ ilana ẹgbẹ, n ṣe ni Jandor n bẹ lati ibi kan si omiran’’

‘’O gbiyanju lati gba ẹgbẹ lọwọ awọn to ni ẹgbẹ, eleyii ti wọn ko gba a laye ko ṣe.’’

‘’Iwadii ta a se fihan pe Jandor kii ṣe ọmọ Eko ni’’

Aworan

“Ọmọ Eruwa nipinlẹ Oyo ni baba Jandor, ti iya rẹ si jẹ Awori nipinlẹ Ogun”

Abiola Ishmael wa tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe ‘’Iwadii wa fihan pe Jandor kii ṣe ọmọ ipinlẹ Eko, amọ ọmọ Eruwa nipinlẹ Oyo ni baba Jandor, ti iya rẹ si jẹ Awori.’’

‘’Nitori naa o yẹ ki o fi ara balẹ ni lati bọwọ fun awọn agba to ba ni ipo.’’

‘’Ki o lọ tun iwa ara rẹ ṣe, ti o ba fẹ duro ninu ẹgbẹ lai yaju si ẹnikẹni ninu ẹgbẹ.’’

‘’Igba akọkọ kọ niyii to n hu iwa ti ko tọ si awọn ẹgbẹ, ti wọn si n fi ori jin amọ o ti kọja aye rẹ bayii.’’