Hamas ṣetán láti dáwọ́ ogun dúró lẹ́yìn tí Israel pinnu láti ṣe ìkọlù sí ìlú Rafah

Aworan awọn eeyan Gaza

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn olori ẹgbẹ Hamas ti sọ pe awọn ṣetan lati kọwọ bọ iwe adehun lati dawọ ogun duro ni ẹkun Gaza.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita ni ẹgbẹ Hamas ti fidi rẹ mulẹ pe awọn ti sọ ipinnu awọn fun olupẹtusija lati Egypt ati Qatar.

Wọn ko tii sọ ẹkunrẹrẹ igbesẹ yii lori igba ti wọn fẹ dawọ ogun duro fun ati bo ya wọn maa tu awọn ọmọ Israel to wa ni igbekun ni Gaza silẹ.

Awọn eeyan Gaza dunnu

BBC ri oniruuru fọto awọn eeyan ni Gaza nibi ti wọn ti n dunnu nita ile iwosan al-Aqsa laarin gbungbun Gaza.

Awọn ọmọde n fo fayọ kaakiri, awọn eeyan n yọ bẹẹ ni wọn n lu ilu lati dunnu.

Aworan awọn eeyan ni Gaza

Oríṣun àwòrán, AP

‘’Imọran ti Israel ko faramọ wa ninu adehun to wa nilẹ’’

Ileeṣẹ iroyin Reuters ni ọkan lara awọn adari Israel sọ pe Hamas gba imọran ati da ogun duro to tẹ wọn lọrun.

Iroyin naa tun sọ pe adari Israel ọhun ni awọn nnkankan wa ninu adehun naa ti Israel ko le gba laelae.

Ọrọ Hamas fawọn eeyan ni ireti lẹyin ọpọlọpọ ijororo

Aworan kẹtẹkẹtẹ pẹlu ẹru lẹyin

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọrọ ti Hamas fi lede pe awọn ṣetan lati dawọn ogun duro waye lẹyin bi ọsẹ meloo kan ti ọpọ ijororo ti waye pẹlu orilẹede Amẹrika, Qatar ati Egypt.

Ni bayii, ko tii han sita koko nnkan to wa ninu adehun ti Hamas gba lati fọwọ si.

Amọ, laipẹ yii, awọn iroyin kan ti a ko le fidi rẹ mulẹ sọ pe ọkan lara ohun to wa ninu adehun naa ni pe Hamas yoo tun awọn Israel ti wọn ko ni igbekun silẹ nigba ti Israel naa yoo ṣi tu awọn ọmọ Palestine to wa lẹwọn lọdọ wọn silẹ.

Ẹgbẹ Hamas n fẹ ki ogun naa pari patapata, amọ, Israel ti sọ pe awọn ko le gba laelae.

Ọrọ ti Hamas sọ yii waye lẹyin ti Israel ti sọ fun igba akọkọ wi pe kawọn eeyan Palestine kuro ni apa guusu Gaza ni Rafah ṣaaju ikọlu ti awọn fẹ ṣe sibẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọmogun IDF sọ pe Israel n ṣe agbeyẹwo adehun ati da ogun duro

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọmogun orilẹede Israel, Daniel Hagari sọ fawọn akọroyin wi pe Israel n ṣe agbeyẹwo adehun jogun o mi ti Hamas ti gba lati buwọlu.

Hagari sọ pe ‘’a n wo gbogbo ibeere ati idahun finifini.

A ṣi maa roo daadaa lori ati gba awọn eeyan wa ti wọn ko ni igbekun pada.

Amọ ṣa, a ṣi wa ni ẹkun Gaza, a o ṣi tẹsiwaju nibẹ lọwọ yii.’’

Ẹgbẹ Hamas sọrọ yii lẹyin ti olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu leri pe Israel ṣi maa ṣe ikọlu silu Rafah to wa lapa guusu Gaza lai nan an ni ọrọ ati dawọn ogun duro to n lọ lọwọ.

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ sọ pe ‘’ọrọ naa ku sọwọ Israel bayii.’’

Ninu ọrọ ti Hamas fi lede lori itagun igbọrọkaye wọn ni wọn ti sọ pe adari awọn, Ismail Haniyeh ba olootu ijọba Qatar, Sheikh Mohammed bin Abdulrahman AI Thani ati minisita ọgbọn inu orilẹede Egypt, Abbas Kamel sọrọ lori foonu ti o si sọ fun wọn pe Hamas ti gba lati kọwọ bọ iwe adehun ati da ogun duro.

A ó tẹ̀síwájú ìkọlù wa sí Gaza títí di ìgbà tí a ó fi rẹ́yìn Hamas – Ìjọba Israel

Benjamin Netanyahu

Oríṣun àwòrán, getty images

Olootu ijọba orilẹede Israel, Benjamin Netanyahu ti sọ pe orilẹede naa yoo kọlu ilu Rafah, to wa lagbegbe ila oorun Gaza.

Netanyahu ni ko si ohun ti yoo yẹ ikọlu naa bo tilẹ jẹ pe ọrọ ajọsọ lati lati dawo ogun duro n waye laarin rẹ ati ẹgbẹ ọmọ ogun Hamas.

Ọrọ yii lo n jade ni bi idunadura ṣe n lọ lọwọ laarin ikọ mejeji lori bi wọn yoo ṣe fopin si ogun naa.

Nibi ipade kan pẹlu awọn mọlẹbi awọn to wa ni igbekun Isreal ati Hamasa ni ọgbẹni Netanyahu ti sọ pe awọn yoo kọlu Hamas lai fi ti ijiroro to n lọ lọwọ laarin awọn mejeji ṣe.

Ọrọ olotu ijọba naa lo n waye lẹyin ti ijọba ilẹ Amẹrika kilọ pe ikọlu kankan ko gbọdọ waye ni Rafah ayafi ti ikọlu ọhun ko ba ni pa awọn araalu lara.

Ninu ifọrọwerọ kan lori ẹrọ ilewọ pẹlu Netanyahu, Aarẹ Amẹrika, Joe Biden jẹ ko di mimọ pe oun ko faramọ ikọlu si Rafah.

Akọwe ajọ UN, Antonio Guterres naa ti sọ pe ikọlu si Rafah ko ni ṣe itẹwọgba.

Atẹjade kan lati ọọfisi ijọba Amẹrika tun ti juwe ikọlu si Rafah gẹgẹ ọhun bii “ikọja aye.”

Idi ti rafah fi ṣe pataki

Idaji nnkan bii miliọnu meji abọ eeyan to n gbe ni Gaza lo ti salọ si Rafah latari ogun to n waye lawọn agbegbe to ku.

Bo tilẹ jẹ pe abo diẹ wa lori awọn eeyan to wa nibẹ, wọn ko ni anfani si ounjẹ, omi to mọ geere ati oogun fun itọju.

Ṣaaju ni ileeṣẹ iroyin Reuters ti kọkọ jabọ pe Israel ko ni kọlu Rafah ti wọn ba fẹnuko lori adehun alaafia pẹlu Hamas.

Amọ Netanyahu ti fidi rẹ mulẹ pe awọn yoo tẹsiwaju ninu ogun ọhun titi ti yoo fi tẹ Israel lọrun.

Netanyahu sọ pe “A maa wọ inu Rafah, a maa pa gbogbo ọmọ ẹgbẹ Hamas to wa nibẹ boya a fẹnuko lori adehun alaafia tabi bẹẹ kọ titi ti a o fi bori ogun naa.”