Ìjọba fòfin de TikTok, Telegram àti 1XBet

Aworan foonu kan pẹlu awọn ohun elo app

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba orilẹẹede Somalia ti fofin de ikanni ayelujara TikTok, Telegram ati ikanni tẹtẹ tita 1Xbet lorilẹede naa.

Minisita eto ibaraẹnisọrọ lorilẹede naa, Jama Hasan Khalif, kede rẹ ninu atẹjade kan.

Jama Hasan Khalif pa a laṣẹ ninu atẹjade naa pe ki “awọn ileeṣẹ ikansiraẹni lati fofin de awọn oju opo naa, eyi ti awọn agbesumọmi atawọn ẹgbẹ buburu mii n lo lati pin awọn aworan ti ko ṣe e wo, to fi mọ iroyin ẹlẹjẹ kiri.”

Ṣaaju aṣẹ yii ni ẹgbẹ agbesumọmi al Shabaab ti kọkọ maa n pin awọn ohun ti wọn n ṣe loju TikTok.

Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti Aarẹ Hassan Sheikh Mohamud kede pe ijọba oun yoo bẹrẹ akọlu si al Shabaab lọna ati yanju ẹgbẹ naa laarin oṣu marun un si asiko yii.

Ajọṣepọ to dan mọran lo wa laarin al Shabaab ati ẹgbẹ alakatakiti ẹsin al Qaeda.

Ileeṣe iroyin Reuters jabọ pe TikTok, Telegram ati 1Xbet ko tii sọ ohunkohun lori aṣẹ tuntun ọhun.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣe Kẹjọ, ọdun 2024 yi ni ijọba Somalia fun awọn ileeṣẹ ikansiraẹni lati fofin de awọn oju opo mẹtẹta naa lorilẹ-de ọhun.

Ẹwẹ, yatọ si Somalia, lara awọn orilẹ-ede mii to ti fofin de Tiktok ni Afganistan, Armania, Bangladesh, Iran, Jordan atawọn orilẹ-ede mii.