Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin Foluke Daramola àti Páátọ̀ Agbala Gabriel tó ń kọ́lé fún Iya Ibeji Omo Arayele

Aworan Pasitọ Agbala Gabriel, iya ibeji ọmọ arayele ati Folukẹ Daramọla

Oríṣun àwòrán, Agbala Gabriel Global PAGE/folukedaramolasalako

Nigba ti iroyin jade pe iranwọ ti dide fun gbajumọ agba oṣere tiata, Arabinrin Adenikẹ̀ Adegboye, ti ọpọ mọ si Iya ibeji ọmọ araye le, ti wolii kan nilu Ibadan si ti n kọ ilegbe fun.

Inu ọpọ eeyan lo dun dẹyin fun oju aanu yii, ti wọn si n kan saara si wolii naa fun ọwọ ọrọ to na si iya ibeji to n se aisan ọhun.

Amọ o ya ni lẹnu pe awuyewuye ti n waye bayii lori ọrọ ile gbigba ati ile kikọ fun gbajumọ osere naa.

Gẹgẹ bi ọrọ naa ṣe n lọ, lẹyin ti Pasitọ ijọ Agbala Gabriel bẹrẹ ile tuntun kikọ fun agba oṣere naa, ni ọkan ninu awọn oṣere tiata ni Naijiria, Folukẹ Daramọla jade sita lori ayelujara lati ṣalaye pe ọrọ naa ko ri bi ọpọ ṣe n ro o.

Awọn ololufẹ iya Ibeji n fi eebu ara ati ọrọ kobakungbe bu Foluke daramola

Foluke ni wọn ti gba ilegbe saaju fun Iya ibeji ọmọ araye le nilu Ikorodu nitori ati le e moju to itọju rẹ nile iwosan.

Awuyewuye naa ti le de ibi pe ọpọ awọn ololufẹ igun mejeeji ti n tahun si ara wọn.

Koda, awọn kan tilẹ n fi eebu ara bu Folukẹ Daramọla pẹlu oriṣiriṣi orukọ kobakungbe ti wọn fi n bu u.

Amọ ṣa, Folukẹ Daramọla naa ti jade lati sọko ọrọ ranṣẹ si awọn to n bu ẹnu atẹ lu u lori ọrọ to sọ nipa ile tuntun ti wọn fẹ kọ naa.

Alaye Foluke ni pe ile ti wn n kọ naa le e ṣokunfa ifasẹyin fun ilera iya ibeji ọmọ araye le.

Bawo ni ọrọ yii ṣe bẹrẹ?

Aworan Iya ibeji omo arayele pẹlu Folukẹ Daramọla

Oríṣun àwòrán, folukedaramolasalako/instagram

Ni ọdun 2022 ni gbajumọ oṣere tiata ati ẹlẹyinju aanu, Folukẹ Daramọla pariwo sita pe ojojo n ṣe ogun iya ibeji ọmọ arayele, ara rẹ ko si da.

Ni ọjọ karun un oṣu keje ọdun 2022 ni Folukẹ Daramọla gbe fidio kan jade loju opo instagram rẹ pe agba oṣere naa nilo iranwọ fun itọju kiakia.

Folukẹ̀ Daramọla ya fidio bo ṣe lọ ki iya ibeji ọmọ araye le ni ile iwosan. Eyi lo pe ọpọ akiyesi si ipo ilera agba oṣere naa.

“Ẹ jọwọ, ẹ jẹ ka maa ranti iya ibeji ninu adura wa, ki a si fi iranwọ owo yoowu ti ẹ ba lagbara ṣọwọ si inu aṣuwọn ifowopamọsi wọn.”

Pasitọ ijọ Agbala Gabriel nawọ iranwọ

Aworan pasito ijọ agbala Gabriel global ati iya ibeji omo arayele

Oríṣun àwòrán, Agbala Gabriel Global PAGE

Lẹyin ti BBC News Yoruba ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun ọmọ agba oṣere iya ibeji ọmọ arayele, arabinrin Aderonkẹ lori ipenija wọn ni alufaa ijọ Agbala Gabriel nilu Ibadan dide iranwọ lati kọ ile fun un.

Ilẹ naa ti o ti n sun mọ ipele ati pari bayii.

Alagba naa ni wọn gbe agba oṣere ọhun wa fun itọju ni ọdọ oun ni ti ara rẹ si tun ti n ya.

Ọmọbinrin mama Ibeji ọmọ arayele fi idi igbesẹ naa mulẹ.

Folukẹ Daramọla sọrọ sita pe ile naa yoo ṣe ọpọ akoba fun iwosan Iya ibeji ọmọ araye le

Foluke Daramola ati iya ibeji ọmọ arayele

Oríṣun àwòrán, other