Ìyá, bàbá àti oͅmoͅ méjì wà lára àwọn tó kú nígbà tí ‘Container’ ṣubú lé oͅkòͅ akérò l‘Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, Lasema

Ileesͅeͅ oͅloͅpaa nipinleͅ Eko ti fi idi reͅ muleͅ pe idile kan sͅoso wa lara peͅlu awoͅn to ba isͅeͅleͅ ijamba oͅkoͅ to waye ni agbegbe Ojueͅleͅgba loͅ.

Awoͅn moͅleͅbi naa ni baba, iya, oͅmoͅkunrin kan ati oͅmoͅbinrin kan wa, ti wọn wa lati inu moͅleͅbi kan naa, ni woͅn sagbako isͅeͅleͅ naa.

Agbeͅnusoͅ fun ileesͅeͅ oͅloͅpaa nipinleͅ Eko, Benjamin Hundeyin ni orukoͅ awoͅn moͅleͅbi meͅrin naa ni Emeka Okoli to jeͅ baba, Ifeyinwa Okoli to jeͅ iya, Chidiebube Okoli to jeͅ oͅmoͅkunrin ati Ifechukwu Okoli to jeͅ oͅmoͅbinrin woͅn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Lasema

Awoͅn miran ti woͅn ba isͅeͅleͅ naa loͅ ti ijoͅba ipinleͅ Eko tun darukoͅ woͅn ni Basirat Olatokumbo King to jeͅ obinrin, Blessing Isioma to jeͅ obinrin, Abdulrahman Okoya Sunday to jeͅ okunrin ati arakunrin Felix John Ifeanyi.

Titi di asiko yii, awoͅn orukoͅ meͅrin ti ijoͅba sͅI fi orukoͅ woͅn lede niyeͅn ninu awoͅn eniyan to gbeͅmi mi ninu isͅeͅleͅ naa.

Ijoͅba ni o kere tan, eniyan meͅsan an lo ku ninu isͅeͅleͅ naa, ti eniyan kan si jajaye amoͅ ti oun gba itoͅju loͅwoͅ ni ileewosan.

Osͅojumikoro soͅ ohun ti oju reͅ ri lasiko isͅeleͅ naa

Agbegbe afara Ojuelegba ni ipinleͅ Eko ni ipinleͅ Eko ni isͅeͅleͅ naa tii waye.

Oͅkoͅ nla to gbe koͅntena lo jaboͅ si ori oͅkoͅ akero to ti ko awoͅn eniyan kun si inu oͅkoͅ.

Arakunrin muyidin ti isͅeͅleͅ naa sͅoju reͅ ni oͅkoͅ akero naa lo n gbe ero nibi eͅnu afara naa lasiko ti oͅkoͅ to gbe koͅntana naa feͅ gun ori afara.

‘’bi oͅkoͅ tirela naa se feͅ gun oke bayii, ni ko lee gun oke, to si beͅreͅ sini pada seͅyin, ki koͅntena to gbe naa si reboͅ si ori oͅkoͅ akero.’’

‘’O kere tan eniyan meͅwaa lo gbeͅmi mi ninu isͅeͅleͅ naa, ti obinrin kan si jajaboͅ’’

Eͅlomiran ti isͅeͅleͅ naa sͅoju reͅ ni ko yeͅ ki tirela maa gba ori afara naa, isaleͅ lo yeͅ ki woͅn maa gba, amoͅ woͅn ni awoͅn to ma n gba owo loͅwoͅ woͅn lo jeͅ ki woͅn maa gba ori afara naa.

‘’Sanwo-Olu pasͅeͅ ki awakoͅ tirela naa foju baleͅ eͅjoͅ to fi moͅ eͅni to ni koͅntena’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Lasema

Gómìna ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti pàṣẹ pé kí wọ́n lọ fojú awakọ̀ àti ẹni tó ni ọkọ̀ container tó ṣubú pa àwọn ènìyàn ní agbègbè Ojuelegba lọ́jọ́ Àìkú ọjọ́ Kọkàndínọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní ọdún 2023 winá òfin.

Sanwo-Olu ní ó pọn dandan láti gbé àwọn ènìyàn náà tó ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá lọ sí ilé ẹjọ́ láti lọ kojú ìgbẹ́jọ́ kó le jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn mìíràn.

Gómìnà Sanwo-Olu nígbà tó ń bá àwọn ènìyàn àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ náà ní ìjọba ìpínlẹ̀ Eko kò ní fi àyè gba àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí ẹ̀dá kan láti máa ṣekúpa àwọn ènìyàn tó ń wá oúnjẹ òjọ́ wọn.

‘’Awoͅn igba miran ti iru isͅeͅleͅ yii ti waye ni Ojuelegba’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, FRSC

Ki isͅeͅleͅ yii to waye ni awoͅn isͅeͅleͅ miran bii iru ti eͅ naa ti sͅeͅlͅe ni ori afara Ojuelegba ati awoͅn agbegbe miran ni ipinleͅ Eko.

Ni Osu Kefa, odun 2018 ni oͅkoͅ akero to gbe plywood subu lori oͅkoͅ akero mͅta ati oͅkoͅ miran.

Awoͅn meji lo ku ninu isͅeͅleͅ naa, ti oͅpoͅ si farapa.

Ni Oͅdun to koͅja ni iru isͅeͅlͅe yii waye ni Oͅjoͅ Karundinlogun, Osu Kini , oͅdun 2022 ti koͅntena kuro loju popo to si sub ulu barricade to si duro sibeͅ .

Oͅpoͅ eniyan ni ko ba isͅeͅleͅ naa loͅ kani barricade naa ko daa duro.

Ijoͅba ipinleͅ Eko ti ni awoͅn yoo sͅe ofintoto direͅba oͅkoͅ naa, ti yoo si foju ba ileeͅjoͅ to fi moͅ awoͅn to loͅwoͅ ninu isͅeͅleͅ naa.