Ọkọ̀ ojú omi dànù ní agbami òkun, èèyàn 39 di àwátì

Ọkunrin kan joko si ori ọkọ oju omi ni agbami Okun

Oríṣun àwòrán, US COAST GUARD

Isẹlẹ ibi kan ti waye ni eti okun Florida lorilẹede Amẹrika nibi ti eeyan mọkandinlogoji ti di awati.

Isẹlẹ naa waye lasiko ti ọkọ oju omi kan dojude lalẹ ọjọ Satide, ti awọn osisẹ agbofinro to n sọ eti okun nilẹ Amẹrika si ti n wa wọn.

Awọn alasẹ ni wọn isẹlẹ naa to leti ni aarọ ọjọ Isẹgun lẹyin ti awọn apẹja sawari ọkunrin kan to rọ mọ eti ọpa kan to wa lori ọkọ oju omi jina rere bii maili marundinlaadọta si ilu Fort Pierce.

Alaye bi isẹlẹ naa se waye ree lẹnu ọkunrin ti ori ko yọ:

Ọkunrin ti ori ko yọ naa ni ilu Bimini ni Bahamas ni awọn ti gbera fun irinajo ọhun ni alẹ ọjọ Satide amọ ti wọn se alabapade ijamba nitori ọju ọjọ ti ko dara.

Awọn alasẹ ilẹ Amẹrika sọ pe ọkọ oju naa le wa lara awọn to n yọ awọn eeyan kọja lọ sorilede miran lati ipasẹ oju omi.

Gẹgẹ bi ọkunrin ti ori ko yọ naa, ti wọn ko tii se idamọ iru eeyan to jẹ ti wi, ko si eyikeyi ninu awọn ero inu ọkọ oju omi naa to wọ ẹwu gbẹmiro loju omi ( Life Jacket).

Awọn ẹsọ oju omi ni Miami n lo ọkọ oju omi ati ti ofurufu lati se awari awọn to kagbako ijamba:

Wayi o, awọn ẹsọ oju omi nipinlẹ Miami ti n lo ọkọ oju omi ati ti ofurufu lati se awari awọn eeyan to ri sinu agbami okun naa.

Amọ titi di san ọjọ Isẹgun, wọn ko tii ri ẹnikankan to ye isẹlẹ naa.

Erekusu Bimini lo wa ni ẹkun iwọ oorun Bahamas, eyi to to ọgọrin Maili si Miami.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Iru awọn isẹlẹ ki ọkọ oju omi danu wo lo ti waye sẹyin:

Igbesẹ ki ọkọ oju omi maa danu kii se tuntun lawọn agbegbe ti omi wa ni Florida.

Eyi ko si sẹyin bi ọkọ oju omi to maa n gbe awọn ajeji se maa n kun akunfaya lori omi.

Ọpọ awọn ero oju omi naa si ni wọn jẹ atipo lati Cuba pẹlu Haiti, ti wọn fẹ gba ẹburu wọ ilẹ Amẹrika.

Ni ọjọ Ẹti to kọja ni ẹsọ eti okun kan fi ẹsun sun pe oun ri awọn ọmọ ilẹ Haiti to to mejidinlaadọrun niye, ti wọn kun inu ọkọ oju omi bamu lati agbegbe Bahamas.