Àwọn àgbébọn kan fẹ́ jọ́wọ́ ohun ìjà wọn fún ìjọba láti kẹ̀yìn síwà ọ̀daràn – Ribadu

Awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Defence/HQ

Olubadamọran pataki si Aarẹ Bola Tinubu lori eto aabo, Mallam Nuhu Ribadu ti sọ pe awọn agbebọn kan ti ṣetan lati jọwọ ohun ija oloro wọn fun ijọba.

Ribadu ni ijọba apapọ ti bẹrẹ ijiroro pẹlu awọn eeyan naa lọna ati gba ohun ija ọwọ wọn ati bi wọn yoo ṣe pada di araalu to n bọwọ fun ofin.

O ni “mo gbagbọ pe Ọlọrun a jẹ ko ṣeeṣe fun wa, a ti n ba wọn sọrọ nitori pe ọmọ iya wa naa ni wọn jẹ.”

Ṣaaju ni ijọba apapọ ti kọkọ sọ pe oun ti bẹrẹ iṣẹ lori awọn janduku naa bo tilẹ jẹ pe ko sọ ni pato awọn igbesẹ to n gbe.

Ribadu ni ọpọ ayipada lo ti waye lati igba ti ijọba tuntun ti gori, paapaa nipa iye eeyan ti awọn agbebọn n ṣekupa loṣoṣu.

Nuhu Ribadu

Oríṣun àwòrán, Nuhu Ribadu

Ṣugbọn ṣe iṣoro eto abo ti dopin?

O ni “bayii ti eeyan ba lọ si agbegbe Niger Delta, yoo ri pe ọpọ iṣẹ ni a ti ṣe nibẹ.

“Ti ẹ ba de awọn agbegbe kan nibẹ tẹlẹ, nnkan bii aadọta agọ ọlọpaa ni awọn agbebọn dana sun, ṣugbọn wọn ti pada ṣi awọn agọ ọlọpaa naa bayii.

“Ni itẹsiwaju, ati fopin si ‘sit at home’ ti wọn n ṣe ni iha ila oorun tẹlẹ, iye iṣekupani to n waye nibẹ si ti dinku ju atijọ lọ.”

Olubadamọran Aarẹ naa sọ siwaju si pe ijọba ti ṣekupa pupọ ninu awọn adari awọn agbebọn to n da alaafia ilu ru ṣaaju asiko yii.

Iroyin sọ lẹnu ọjọ mẹta yii pe awọn olugbe ilu to le lọgọrun lo ti salọ bayii ni ijọba ibilẹ Malumfashi ati Kankara nipinlẹ Katsina latari ikọlu lemọlemọ awọn agbebọn nibẹ.

Awọn eeyan ilu naa sọ pe awọn janduku n pa awọn aja awọn latari eto abo tomẹhẹ nibẹ.

Ni ijọba ibilẹ Kankara, iṣoro eto abo tun ti n pada sawọn agbegbe kan nibẹ.

Olugbe ilu naa kan to ba BBC sọrọ ṣalaye pe eeyan le wa ninu ile rẹ ki ibọn ṣadede lọ ba nibẹ.

Gbogbo igbiyanju lati kan si ileeṣẹ ọlọpaa lori ọrọ yii lo wa ja si pabo.