Ìdí tí mo ṣe fẹ́ yọ ayédèrú ìdí ńlá tí mo ní- Sophie

idi

Oríṣun àwòrán, @Sof

Onkọroyin lori ayelujara to tun jẹ gbajugbaja lori ẹrọ mohunmaworan, Sophie Elise ṣe iṣẹ abẹ afikun idi rẹ nigba to wa lọmọ ogun ọdun.

O ṣalaye pe, ifẹ lati ni idi to tobi bii ti ojulowo ọmọbinrin lo jẹ ki oun diju ṣe iṣẹ abẹ naa ni ọdun marun un sẹyinsun ohun o.

Arabinrin yii ṣapejuwe ara rẹ bi ẹni ti ko lara rara ṣugbọn ti o kan fẹ ṣe afikun diẹ si ibi to ṣe pataki si i ninu ẹya ara rẹ yii.

Oriṣiriṣi awọn eniyan ni wọn n polowo lori ẹrọ ayelujara rẹ ati irufẹ awọn Dokita to le ṣe fifi idi tobi to fi mọ ti ilẹ Brazil.

Sophie ri ibi kan ni ilẹ Turkey ti won ti le ṣe iṣẹ abẹ naa ṣugbọn ti owo rẹ fẹ wọn ko too ri ọna abayọ.

Nigba ti o n ṣalaye fun ikọ akọroyin Radio 1 Newbeat, ni tootọ owo naa kere si bi o ti yẹ, pe o yẹ ki o wọn ju bẹẹ lọ.

Ayederu idi n la

Oríṣun àwòrán, facebook

Kini idi ti Sophie ṣe fẹ yọ ayederu idi naa lẹyin ọdun marun un ti o ti fi si?

Kete ti Sophie ti ile iwosan de ni gbogbo ara rẹ ko ti gbadun.

Ilumọọka ni Sophie ni orilẹ-ede Norway nibi to ti n gbe eto oriṣiriṣi sori afẹfẹ to tun ni awọn to le ni ẹgbẹrun ẹẹdẹgbẹta to n tẹlẹe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bakan naa lo mẹnuba awọn ẹgbẹlẹgbẹ awọn ololufẹ rẹ lori ẹrọ ayelujara, ti wọn lodi si ayederu idi nla ti oun ṣe naa.

Awọn eniyan ni iduro rẹ ko dan mọnran bakan naa ni idi nla naa ko ba ẹya ara rẹ toku mu.

Onidi nla

Oríṣun àwòrán, Sophie Elise

Gẹgẹ bi o ti wi, o ni aridaju ti wa fun ohun bayii pe okun ọrun ko yẹ adiyẹ ohun rara ti abamọ si ti n gbẹyin ọrọ bayii.

Ẹni ọmọ ọdun merinlelogun naa ti wa pinnu bayii pe ki wọn gba abẹrẹ fun oun lori idi naa ki wọn si jẹki oun ru diẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ṣiṣe ayederu idi ni ọpọlọpọ aida ninu ti o si ṣeku pa awọn obinrin ilẹ Britain meji ti wọn rin irin ajo lọ si ilẹ Turkey.

O wa ni ohun ti ri i wi pe ara ohun dara pupọ ju iru wahala ti o bara rẹ yi lọ.

Sophie ti wa ri ẹni ti yoo le ba ṣe iṣẹ abẹ daada lẹyin ti o ti o ti ṣe iwadii lori ẹrọ ayelujara.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Sophie ti wa pinnu ninu ọkan rẹ lati ṣe isẹ abẹ naa pẹlu Dokita to mọṣẹ lati din ẹru ẹyin rẹ ku si kekere ti ara rẹ yoo le gbe.

Bayii, sophie ti ronu ara rẹ pe, o dara ki eeyan maa gba bi ara rẹ ṣe ri ki o si maa fun ara rẹ ni iwuri.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ