Ìdí tí a kò ṣe fọwọ́ òfin mú ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn 48 tó ronúpìwàdà l’Ógùn- Ọlọ́pàá

Awon nnkan ija tawon omo egbe okunkun yonda re l'Ogun

Oríṣun àwòrán, SP Omolola Odutola

Lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹta 2024 ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun mejidinlaaadọta (48), jọ̀wọ́ nnkan ija ọwọ wọn ni Ṣagamu, wọn lawọn o ṣẹgbẹ buruku mọ.

Aafin Akarigbo ilẹ Rẹmọ, Ọba Babatunde Ajayi, ni ironupiwada naa ti waye, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ri awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa.

Awọn kan si sọ pe wọn wa nibẹ, wọn lawọn to mọ wọn lo mọ wọn ni.

Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, Abiọdun Alamutu, salaye nibi eto naa pe awọn dariji awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii lati le faaye silẹ fawọn yooku lati ronu piwada ni.

O ni ohun to yẹ ni lati foju wọn han gẹgẹ bi ọdaran, ṣugbọn nitori iwadii ṣi n tẹsiwaju nipa wọn, to si jẹ pe ironupiwada maa n rọ eeyan lọkan, lawọn ṣe fi wọn silẹ.

A fẹ́ẹ́ fún wọn láǹfààní láti padà di ọmọ Naijiria rere ni- Alamutu

Alamutu sọ pe, ‘’gbogbo wa la mọ ikọlu oriṣiiriṣii ta a koju latọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni Ṣagamu, eyi to sọ ọpọlọpọ ẹmi nu.

‘’Ipade ọlọkan-o-jọkan pẹlu ijọba atawọn lọbalọba lo bi igbesẹ yii, o si wa ni ibamu pẹlu ohun ti Ọga agba ọlọpaa, Kayọde Ẹgbẹtokun naa sọ.

‘’Pe kawọn eeyan to ba ni nnkan ija lọwọ lọna aitọ waa ko wọn silẹ. Koda,awọn to ni iwe aṣẹ rẹ gan-an, a rọ wọn lati ko wọn silẹ.

‘’A fun awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa lanfaani lati ko nnkan ija wọn wa nigba ti wọn ti ṣẹleri pe awọn ko ṣẹgbẹ naa mọ.

’’A ṣe bẹẹ lati jẹ ki wọn pada di ọmọ Naijiria rere ni.

‘’A ti ba wọn sọrọ, a jẹ ki wọn mọ pe ẹgbẹ okunkun kọ ni ọna abayọ, yoo wulẹ ba aye wọn ati orukọ ẹbi wọn jẹ ni.

‘’ A ti ṣẹleri lati gba wọn mọra laarin ilu, isẹ ṣi n lọ lọwọ lori ẹ.

‘’A gbagbọ pe awọn ẹgbẹ wọn yooku yoo kẹkọọ lara awọn ti Rẹmọ yii, wọn yoo ronupiwada.’’

‘’Awọn tọwọ ba tẹ ninu ẹgbẹ buruku lẹyin anfaani ta a fun wọn yii la o mu gẹgẹ bi arufin’’

Ẹ má ṣe ta wọ́n nù láàrin ìlú, ẹ fà wọn mọ́ra

Nigba to n sọrọ, Akarigbo ilẹ Rẹmọ, Ọba Babatunde Ajayi, rọ awọn eeyan ilu Ṣagamu lati ma ṣe ta awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to ronupiwada naa nu laarin ilu.

Akarigbo dupẹ lọwọ Gomina Dapọ Abiọdun atawọn ẹṣọ alaabo Ogun, fun iṣẹ takun-takun ti wọn ṣe lati jẹ ki eto ironupiwada ati aforiji yii ṣee ṣe.

Aworan Kabiyesi Akarigbo nibi ti wọn ti n ṣeto idarijin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun

Oríṣun àwòrán, SP Omolola Odutola

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣiwaju?

Igba meji ọtọọtọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye ati Ẹyẹ, kọ lẹta aforiji si Aakrigbo atawọn ọba Rẹmọ yooku ninu oṣu kin-in-ni ọdun 2024 yii.

Wọn ti kọkọ kọ lẹta naa lọtọọtọ ki wọn too tun jọ kọ akọpọ.

Ninu awọn lẹta naa ni wọn ti lawọn ko ṣẹgbẹ okunkun mọ, ki kabiyesi foriji awọn.

Ṣugbọn nigba naa, Aafin Akarigbo lawọn ko mọ awọn to n kọ lẹta ọhun, nitori wọn ko jade kaye ri wọn.