Èèwọ̀ àti àròsọ mẹ́wàá tó jẹ́ irọ́ àmọ́ tí àwọn èèyàn gbàgbọ́ nípa nǹkan oṣù obìnrin

Aworan paadi nnkan osu

Oríṣun àwòrán, Other

Ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo gbagbọ pe eniyan ara ọtọ ni awọn obinrin jẹ, akanṣe iṣẹ Olodumare si ni wọn pẹlu nitori iṣẹda wọn.

Ọkan gboogi lara ohun to si mu ki awọn obinrin jẹ eniyan ọtọ ni ṣíṣe nnkan oṣu, eyi to jẹ ki wọn le maa loyun, ati bímọ.

Akọsilẹ fihan pe idaji awọn eeyan to wa laye ni o n ṣe nnkan oṣu.

Amọ, bi nnkan oṣu obinrin ti ṣe pataki to yii, sibẹ oniruuru awọn igbagbọ ti ko fi idi mulẹ lode oni, l’awọn eeyan n sọ nipa rẹ.

Wọnyi ni awọn arosọ tabi eewọ nipa nnkan oṣu obinrin ti ko fidi mulẹ:

Obinrin ko le loyun to ba ni ibalopọ lasiko nnkan oṣu

Ọpọ lo gbagbọ pe obinrin to ba ni ibalopọ lasiko nnkan oṣu rẹ ko le loyun.

Amọ, awọn onimọ ijinlẹ sayẹnsi tako eyi pe ko rí bẹẹ rara.

Awọn dokita ṣalaye pe eleyii niṣe pẹlu bi obinrin kọọkan ṣe maa n ri nnkan oṣu wọn.

Wọn ni ọjọ mejidinlọgbọn l’awọn obinrin mii maa n ri nnkan oṣu loṣooṣu, nigba t’awọn mii ṣi maa n ri ti wọn laarin ọjọ mọkanlelogun l’oṣooṣu.

Bakan naa ni wọn ṣalaye pe atọ ti ọkunrin ba da si oju ara obinrin lasiko nnkan oṣu le wa nibẹ di ọjọ ti ẹyin obinrin naa yoo de ile ọmọ rẹ, eleyii to le fa oyun.

Lilo oogun ifetosọmọbibi lati da nnkan oṣu duro

Ọpọ lo maa n sọ pe o lewu fun ilera obinrin lati maa loogun ifetosọmọbibi fun idaduro nnkan oṣu.

Awọn akọṣẹmọṣẹ onisegun sọ pe eyi ko mu ewu kankan dani.

Awọn dokita ṣalaye siwaju si pe nnkan oṣu maa n da awọn obinrin mii laamu.

Inu maa n run awọn obinrin mii ti wọn ba n ṣe nnkan oṣu lọwọ.

Koda, nnkan oṣu maa n da awọn obinrin gunlẹ debi pe wọn o ni le lọ si ibi kankan.

Eyi lo maa n jẹ ki awọn obinrin mii maa lo oogun ifetosọmọbibi lati da a duro, eyi t’awọn dokita ti sọ pe ko si ewu kankan nibẹ.

Obinrin ko gbọdọ wẹ lasiko nnkan oṣu

Awọn kan gbagbọ pe o lewu fun obinrin lati wẹ lasiko ti o ba n ṣe nnkan oṣu lọwọ.

Bo ya nitori wi pe omi gbigbona maa n ṣe okunfa ki ẹjẹ maa jade lara eeyan tabi tori omi tutu maa n dena ki ẹjẹ jade lara eeyan ni.

Amọ, awọn onimọ sayẹnsi ti sọ pe obinrin le wẹ laifoya lasiko ti o n ṣe nnkan oṣu.

Wọn ni iwẹ wiwẹ yoo jẹ ki ara ji pipe si ni.

Awọn dokita ni lilo omi gbigbona lati wẹ gan an le ṣe iranwọ fun nnkan oṣu lati wa wọọrọrọ.

Wọn ni ko si idi kan to ni ki eeyan maa wẹ nitori pe o n ṣe nnkan oṣu lọwọ.

Aworan paadi nnkan osu

Oríṣun àwòrán, Other

Nnkan oṣu n ba oogun ibilẹ jẹ

Igbagbọ Yoruba ni pe obinrin to ba n ṣe nnkan oṣu ko mọ rara, ohun ẹgbin si ni.

Irufẹ obinrin bẹẹ si ni wọn kii jẹ ko fi ọwọ tabi ara kan oogun ibilẹ nitori igbagbọ pe oogun naa yoo bajẹ ni.

Koda, obinrin to ba n ṣe nnkan oṣu ni wọn kii gba ko jokoo ti ẹni to ni oogun ibilẹ lara nitori igbagbọ pe, oogun naa yoo bajẹ.

Bẹẹ ni irufẹ obinrin bẹẹ ko gbọdọ ja ewe ati egbo tabi fi ọwọ kan wọn, titi ti nnkan oṣu rẹ yoo fi pari.

Ṣugbọn ko si imọ sayẹnsi ati ẹri to daju lati fi idi igbagbọ yii mulẹ.

Obinrin to n ṣe nnkan oṣu ko le jọsin fun Ọlọrun

Igbagbọ mii ti ko fi idi mulẹ nipa nnkan oṣu obinrin ni pe obinrin to ba n ṣe nnkan oṣu ko le jọsin niwaju Oluwa, ko jẹ itẹwọgba.

Bi o tilẹ jẹ pe ẹsẹ Bibeli ni majẹmu lailai ati Kurani tọkasi eyi, ti awọn Kristẹni alaṣọ funfun atawọn Musulumi si n tẹle, ti awọn ẹlẹṣin abalaye naa si fara mọ igbagbọ yii, sibẹ awọn ọlaju ati imọ sayẹnsi kan tako igbagbọ naa pe ko tọna, ti ọpọ obinrin miran si maa n jọsin lasiko ti wọn n ṣe nnkan oṣu lọwọ.

Ọkunrin to ba ni ibalopọ pẹlu obinrin to n ṣe nnkan oṣu yoo ku

Awọn mii tun gbagbọ pe ọkunrin to ba ni ibalopọ pẹlu obinrin to n ṣe nnkan oṣu lọwọ yoo ku.

Eyi si maa n mu ki ọpọ ọkọ ninu ile yẹra fun iyawo rẹ to ba n ṣe nnkan osu, yatọ si ero ti wọn tun ni pe iru obinrin bẹẹ ko mọ.

Amọ iwadii imọ ijinlẹ lode oni ti tako igbagbọ naa, to si ni ko si ewu kankan ninu ki obinrin ni ibalopọ pẹlu ọkunrin lasiko to ba n ṣe eela lọwọ, o kan nilo ko wẹ mọ tonitoni ko to wọle tọ ọkunrin ni.

Obinrin maa n ni arun ọpọlọ diẹ diẹ lasiko nnkan oṣu

Igbagbọ karun un nipa nnkan oṣu obinrin ti ko fidi mulẹ ni pe, awọn obinrin to n ṣe nnkan oṣu maa n ṣe gan-gan-gan fun isẹju diẹ lasiko nnkan oṣu wọn.

Idi si ree ti awọn ọkunrin fi maa n ba obinrin sere pe “ṣe nnkan oṣu rẹ tun ti de si ọ ni?”

Ṣugbọn ko si iwadii imọ ijinlẹ kankan to fara mọ ero yii, iwa abuku si ni wọn lo jẹ fawọn obìnrin.

Awọn ounjẹ kan wa ti obinrin ko le ṣe lasiko nnkan oṣu rẹ

Igbagbọ kẹfa nipa nnkan oṣu obinrin ti ko tun fi idi mulẹ ni pe awọn oriṣi ounjẹ kan wa ti ko ni jinna lailai, ti obinrin to n ṣe nnkan oṣu lọwọ ba se e.

Apẹẹrẹ iru ounjẹ bẹẹ ni mọinmọin, ti igbagbọ wa pe yoo pẹ ko to jinna tabi ko ma jinna rara ti obinrin to n ṣe nnkan oṣu ba se e.

Amọ ko si iwadii imọ sayẹnsi tabi ẹri to daju, to fi igbagbọ yii mulẹ.

Awọn obinrin to n gbe pọ maa n ṣe nnkan oṣu lasiko kan naa

Awọn iṣẹ iwadii kan at’awọn eeyan kan maa n sọ pe awọn obinrin to ba n gbe papọ yala nileegbe awọn akẹkọọ tabi ni ibo miran ṣaba maa n ri nnkan oṣu wọn lasiko kan naa.

Amọ, iwadii awọn akọṣẹmọṣẹ dokita onimọ iṣegun ti sọ pe arosọ lasan ni, ko si otitọ nibẹ.

Iwadii naa fidi rẹ mulẹ pe awọn ti iru eyi ba ṣẹlẹ si, o kan ṣe deedee ara wọn ni.

Ọjọgbọn Alexandra Alvvergne ti ile ẹkọ gíga fasiti Oxford lorilẹede UK sọ pe “gẹgẹ bi eeyan, a maa n fẹran awọn arosọ to dun un gbọ leti.

A maa n fẹ ri pe awọn eeyan gba wa gbọ pẹlu ohun ti a ba ṣe akiyesi rẹ.”

O ni imọ ijinlẹ ko fidi rẹ mulẹ pe awọn obinrin to n gbe pọ le maa ṣe nnkan oṣu lasiko kan naa.

Lilo Tampon lasiko nnkan oṣu lewu

Nnkan mii t’awọn eeyan kan maa n sọ ni pe lílo tampon lasiko nnkan oṣu le ṣakoba fun oju ara obinrin.

Tampon jẹ ọkan lara awọn eroja ti awọn obinrin ma n lo lati fi gbe ẹjẹ nnkan oṣu dipo paadi tabi aṣọ.

Wọn ma n ki tampon sinu oju ara wọn, wọn a si fa a jade pada to ba ti to asiko lati paarọ rẹ.

Ohun t’awọn eeyan kan maa n bẹru ni pe lilo tampon le ja awọ ‘hymen’ oju ara obinrin ti ko tii mọ okunrin.

Amọ, awọn onimọ sayẹnsi ti sọ pe irọ nla ni, wọn ni awọ ‘hymen’ yii kii ṣe nnkan ti tampon le ja.

Wọn ni to ba ri bẹẹ ni, awọ ‘hymen’ gan-an ko ba maa ṣe idena fun ẹjẹ to n jade lati oju ara awọn obinrin ti ko tii mọ ọkunrin.

Awọn dokita ni awọ ‘hymen’ maa n ran, nitori naa, ki i ṣe nkan ti tampon le ja.

Bakan naa ni wọn sọ pe oju ara maa n yọ lasiko nnkan oṣu, eyi to tumọ si wọọrọrọ ni tampon yoo wọ ibẹ.