Iléeṣẹ́ ààrẹ tún àlàyé ṣe lórí irú amí ẹyẹ tí ìjọba fí dá àwọn ọmọ ogun tí wọ́n pa ní Delta lọ́lá

Aworan aarẹ Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, FredrickNwabufo

Aarẹ orileede Naijiria Bola Tinubu ti fi ami ẹyẹ da awọn ọmoogun Naijiria ti wọn ṣeku pa ni ipinlẹ Delta lọla.

Lasiko ti isinku wọn waye ni aaye isinku awọn ologun Naijiria to wa ni olu ilu Naijiria, Abuja, ni ikede yi ti waye.

Aarẹ Tinubu,awọn mọlẹbi oloogbe ati awọn olori ileeṣẹ ologun Naijiria to fi mọ awọn Gomina ipinlẹ kọọkan lo pejui sibi ayẹyẹ yii.

Nibi eto isinku naa, aarẹ Tinubu sọ pe ijọba yoo ṣeto eto ẹkọ ọfẹ titi de fasiti fawọn ọmọ awọn ọmọ ogun to padanu ẹmi wọn ni ipinlẹ Delta.

Bẹẹ lo paṣẹ ki awọn eleto tara yanju gbogbo ajẹmọnu to ba tọ si awọn idile awọn ọmo ọgun yi laarin aadorun ọjọ.

Ko tan sibẹ aarẹ tun jẹjẹ ipese ile nibi kibi to ba wu wọn lorileede Naijiria fun awọn idile ọgagun mẹrin to wa laarin wọn ati awọn ọmọ ogun mẹtala to pẹlu padanu ẹmi wọn ninu iṣelẹ buruku yii.

Aarẹ tẹnumọ pe awọn yoo ṣa gbogbo apa lati ri wi pe awọn to ṣekupa awọn ọmọ ogun yi fọju wina ofin.

Aworan ayẹyẹ isinku awọn ọmo ogun Naijiria to waye lAbuja

Oríṣun àwòrán, FredrickNwabufo

Ẹwẹ, ọkan ninu awọn amugbalẹgbẹ aarẹ Tinubu, Bayo Onanuga, ti ṣalaye ẹkunrẹre lori iru ami ẹyẹ ti aarẹ fi da awọn ọmọ ogun to padanu ẹmi wọn yi lọla.

Loju opo rẹ ni Twitter lo fi alaye yi si pẹlu aworan to ṣafihan orukọ ẹnikọọkan ati iru ami ẹyẹ ti aarẹ fi da wọn lọla.

Awọn mẹrin ninu wọn gba ami ẹyẹ MON taa mọ si Member of the Order of the Niger(MON) ti ọkan ninu wọn si gba ami ẹye Federal Republic Medal 1.

Awọn mejila to ku gba ami ẹyẹ Federal Republic Medal 11.

Aworan orukọ wọn ati ami ẹyẹ ti onikaluku gba gẹgẹ bi Onanuga ṣe ṣalabapin rẹ loju opo rẹ ree:

Skip Twitter post

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

Ìsìnkú àwọn ọmọ ogun tí wọ́n pa ní ìpínlẹ̀ Delta yóò wáyé lónìí

Awọn ọmọ ologun ti wọn pa

Oríṣun àwòrán, NIGERIA ARMY

Ileeṣẹ ologun Naijiria ti kede pe Ọjọru, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2024 ni wọn yoo sinku awọn ologun mẹtadinlogun to padanu ẹmi wọn niluu Okuama, nipinlẹ Delta.

Aago mẹta ọsan ni eto isinku naa yoo waye ni itẹ oku awọn ologun apapọ orilẹ-ede Naijiria.

Isinku yii n waye lẹyin ti rogbodiyan laarin Okuama ati Okoloba, pa awọn ṣọja mẹtadinlogun ọhun.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ologun to fi aworan awọn ṣọja to doloogbe naa sita loju opo X wọn ṣe ṣalaye, awọn to padanu ẹmi naa ni:

  • Lt Col AH Ali, the Command Officer, 181 Amphibious Battalion, Nigerian Army,
  • Major SD Shafa (N/13976),
  • Major DE Obi (N/14395),
  • Captain U Zakari (N/16348),
  • Staff Sergeant Yahaya Saidu (#3NA/36/2974),
  • Corporal Yahaya Danbaba (1ONA/65/7274),
  • Corporal Kabiru Bashir (11NA/66/9853),
  • Lance Corporal Bulus Haruna (16NA/TS/5844),
  • Lance Coraporal Sole Opeyemi (17NA/760719),
  • Lance Corporal Bello Anas (17NA/76/290),
  • Lance Corporal Hamman Peter (NA/T82653),
  • Lance Corporal Ibrahim Abdullahi (18NA/77/1191),
  • Private Alhaji Isah (17NA/76/6079),
  • Private Clement Francis (19NA/78/0911),
  • Private Abubakar Ali (19NA/78/2162),
  • Private Ibrahim Adamu (19NA/78/6079),
  • Private Adamu Ibrahim (21NA/80/4795)

Kí lohun tó ti ṣẹlẹ̀ lẹ́yin ikú áwọn ológun náà?

Ọga awọn ọmọ ogun Naijiria, Ọgagun Christopher Musa, sọ pe ileeṣẹ ologun mọ awọn eeyan to pa awọn ṣọja mẹtadinlogun naa.

O ni asiko diẹ lo ku tawọn yoo fi ridi iṣẹlẹ yii patapata, nitori awọn n ṣewadii rẹ gidi.

‘’ Ọgagun A.H Ali ti wọn pa ninu awọn eeyan wa yii, fẹẹ fopin sawọn amookunṣika to wa nidii jiji epo rọbi ni Delta ni wọn fi pa a.

‘’Awọn alajangbila yii naa ni nnkan ija pupọ lọwọ, awọn ni wọn lo anfaani ikọlu yẹn lati pa Ọgagun Ali.’’

Bo tilẹ jẹ pe ibẹrubojo ohun ti awọn ologun le ṣe lati gbẹsan ti mu ilu Okuama ati agbegbe rẹ tuka, sibẹ, awọn ṣọja sọ pe kawọn araalu naa maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ.

Wọn ni ti awọn ba tilẹ n mu awọn ọdaran, ẹni ti ko ba jẹ gbii ninu araalu ko ni i ku gbii.

Tẹ o ba gbagbe, Ọjọbọ, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, 2024, ni awọn ologun mẹtadinlogun naa padanu ẹmi wọn lasiko ipẹtu-saawọ ni Okuama, ipinlẹ Delta.