Gómìnà mi ọ̀wọ́n, Ọlọ́rùn yóò mú ọ ṣàṣeyọrí – Ladoja kí Makinde kú oríire

Seyi Makinde ati Ladoja

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Oyo, Sẹnetọ Rashidi Ladoja ti ki gomina Seyi Makinde ku oriire gẹgẹ bi ajọ eleto idibo, INEC ṣe kede rẹ gẹgẹ bii gomina ti yoo tukọ ipinlẹ Oyo fun saa ọdun mẹrin mii.

Ṣaaju ni gbogbo igba ti ipolongo ibo n lọ lọwọ, Ọgbẹni Ladoja ko figba kankan ṣe atilẹyin fun gomina ṣeyi Makinde dipo bẹẹ, gba gba gba lo wa lẹyin oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Teslim folarin amọ ibo ti pari, ọrọ ti wa yipada bayii.

Bẹẹ si ni agbo oṣelu ni ipinlẹ Oyo le gan to si gbona janjan laarin awọn ẹgbẹ to gbajumọ ju to n du ipo naa amọ wọn ti kede olubori bayii, ko si ariwo mọ ni Oyo.

Ninu ọrọ ikini ku oriire rẹ to wa ninu atẹjade to fi sita, Otun Olubadan ti ilu Ibadan naa, Oloye Rashidi Ladoja ki Gomina Seyi Makinde ku oriire o si tun fi adura ranṣẹ sii pe ki Ọlọrun jẹ ko ṣe aṣeyọri nipa ṣiṣe amuṣẹ ireti awọn eniyan Oyo.

Atẹjade naa ka bayii:

“Nibayii,

Gbogbo ipolongo ibo ti tan

Gbogbo irunu ti tan

Gbogbo irọ pipa ti pari

Eebu,ninaka alebu, rọ alufansa ti tan

Ka maa mọọmọ gbọ ọrọ sodi ti pari

Fifa ipo mọ ara ẹni lọwọ ti dopin”

Ladoja ni gbogbo awọn to n ba ara fa a ti kuro lori itage bayii tawọn ti gbogbo ife ẹyẹ wọn atawọn to si fara pa naa, “wọn ti fi iwọ nikan silẹ bayii.

Ohun to wa ku ẹ ku ni awọn ileri too ṣe”.

Ladoja wa kẹnu bọ adura fun Makinde pe Ọlọrun yoo jẹ ko ṣe aṣeyọri lati ṣe ohun ti awọn eniyan fẹ, bi yoo ṣe tẹ ẹ lọrun ati lati ṣe iṣẹ naa to wa niwaju rẹ.

Ohun tí mo soͅ fún àwoͅn ará Oyo sͅáájú ìdìbò ààreͅ nìyí – Seyi Makinde

Tinubu ati Makinde

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Gomina ipinleͅ Oyo, Seyi Makinde ti so bi o se jiroro peͅlu awoͅn ara ipinleͅ Oyo saaju idibo sipo aareͅ lorileͅede Naijiria.

Seyi Makinde ni o gbegba oroke ninu idibo sipo gomina to waye nipinleͅ Oyo la eͅgbeͅ oselu PDP, amoͅ oludije labeͅ eͅgbeͅ oselu PDP, Atiku Abubakar fidireͅmi ninu idibo sipo aareͅ, Bola Tinubu ti eͅgbeͅ oselu APC si gbegba oroke.

Ohun ti o ya awoͅn eniyan leͅnu nipe awoͅn gomina marun un leͅgbeͅ oselu PDP ni woͅn sͅatileͅyin fun eͅgbeͅ oselu APC lasiko idibo aareͅ naa, ti woͅn si tako oludije sipo aareͅ ti eͅgbeͅ oselu APC.

Ninu ifoͅroͅweroͅ peͅlu Channels TV , Seyi Makinde salaye pe kii se pe boya oun poͅn dandan fun awoͅn eniyan lati dibo yan Bola Tinubu amoͅ awoͅn eniyan onimoͅ ni awoͅn ara ipinleͅ Oyo.