‘Gbogbo ìlérí tí Sanwoolu àti Hamzat ṣe pátápátá ni wọ́n mú ṣẹ l’Eko’ – Ṣé lóòtọ́ ni?

Lati igba ti ikede abajade esi idibo ipinlẹ Eko ti jade ti ajọ INEC si ti kede Gomina Babajide Sanwoolu gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ni awọn eeyan ti n sọ erongba wọn.

Bi awọn alatako atawọn ti o jẹ pe Sanwoolu kọ ni aayo oludije ti wọn fẹ ṣe n sọ ti wọn, bẹẹ naa ni awọn ti Sanwoolu gangan n fi idunu ati ayọ fesi pe oun gaan lo tọ si.

Idi niyi ti BBC Yoruba ṣe fọrọ wa awọn eniyan lẹnu wo lori erongba wọn nipa jijawo olubori Babajide Sanwoolu.

Ajọyọ nipa jijawe olubori Sanwoolu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwoolu/Instagram

Ni ibi ti awọn alatilẹyin rẹ ti n ṣe ajọyọ pe o jawe olubori, lara awọn ti a ba sọrọ mẹnu ba awọn daadaa ti Sanwoolu ati igbakeji rẹ Hamzat ti ṣe ni ipinlẹ Eko.

“Gbogbo ìlérí tí Sanwoolu àti Hamzat ṣe pátápátá ni wọ́n mú ṣẹ l’Eko”.

Eyi ni ohun ti ọkan lara awọn ti inu wọn dun si bi sanwoolu ṣe jawe olubori sọ fun BBC.

Bakan naa ni o mu ẹnu ba iru ato ti Gomina naa la kalẹ nigba to kọkọ n ṣe ipolongo lati lọ fun saa ikini to si tun sọ pe gbogbo aato ọhun patapata ni Sanwoolu gbe yẹwo to si ti wa si imuṣẹ ni Eko.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí